Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Matiu 12:38-45 BIBELI MIMỌ (BM)

38. Ní àkókò náà ni àwọn kan ninu àwọn amòfin ati ninu àwọn Farisi bi í pé, “Olùkọ́ni, a fẹ́ rí àmì láti ọwọ́ rẹ.”

39. Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii.

40. Nítorí bí Jona ti wà ninu ẹja ńlá fún ọjọ́ mẹta tọ̀sán-tòru, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo wà ninu ilẹ̀ fún ọjọ́ mẹta, tọ̀sán-tòru.

41. Àwọn ará Ninefe yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́, wọn yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí wọ́n ronupiwada nítorí iwaasu tí Jona wà fún wọn. Wò ó, ẹni tí ó ju Jona lọ ló wà níhìn-ín.

42. Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín.

43. “Nígbà tí ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ẹnìkan, ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ilẹ̀ gbígbẹ láti sinmi. Ó ń wá ibi tí yóo fi ṣe ibùgbé, ṣugbọn kò rí.

44. Ó bá ni, ‘N óo tún pada sí ilé mi, níbi tí mo ti jáde kúrò.’ Nígbà tí ó débẹ̀, ó rí i pé ibẹ̀ ṣófo, ati pé a ti gbá a, a sì ti tọ́jú rẹ̀ dáradára.

45. Ó bá lọ, ó kó àwọn ẹ̀mí meje mìíràn lẹ́yìn tí wọ́n burú ju òun alára lọ, wọ́n bá wọlé, wọ́n ń gbé ibẹ̀. Ìgbẹ̀yìn ẹni náà wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ìran burúkú yìí.”

Ka pipe ipin Matiu 12