Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 25:13-30 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Dafidi sì pàṣẹ fún àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹ sán idà yín mọ́ ìdí.” Gbogbo wọn sì ṣe bí ó ti wí; òun pàápàá sì sán idà tirẹ̀ náà mọ́ ìdí. Irinwo ninu àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ bá a lọ; igba (200) sì dúró ti ẹrù wọn.

14. Ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin Nabali sọ fún Abigaili, iyawo Nabali pé, “Dafidi rán àwọn iranṣẹ láti aṣálẹ̀ wá sọ́dọ̀ oluwa wa, ṣugbọn ó kanra mọ́ wọn.

15. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọkunrin náà tọ́jú wa, wọn kò sì ṣe ibi kankan sí wa, nǹkankan tí ó jẹ́ tiwa kò sì sọnù nígbà tí a wà pẹlu wọn ní oko.

16. Wọ́n dáàbò bò wá tọ̀sán tòru, ní gbogbo ìgbà tí a wà lọ́dọ̀ wọn, tí à ń tọ́jú agbo ẹran wa.

17. Jọ̀wọ́ ro ọ̀rọ̀ náà dáradára, kí o sì pinnu ohun tí o bá fẹ́ ṣe; nítorí pé wọ́n ti gbèrò ibi sí oluwa wa ati ìdílé rẹ̀, ọlọ́kàn líle sì ni oluwa wa, ẹnikẹ́ni kò lè bá a sọ̀rọ̀.”

18. Abigaili bá yára mú igba (200) burẹdi ati ìgò ọtí waini meji ati aguntan marun-un tí wọ́n ti sè ati òṣùnwọ̀n ọkà yíyan marun-un ati ọgọrun-un ìdì àjàrà gbígbẹ ati igba (200) àkàrà tí wọ́n fi èso ọ̀pọ̀tọ́ dín, ó sì dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

19. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ máa lọ ṣiwaju, èmi náà ń bọ̀ lẹ́yìn,” ṣugbọn kò sọ fún ọkọ rẹ̀.

20. Bí ó ti ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ lọ, tí ó dé abẹ́ òkè kan, ó rí i tí Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ ń bọ̀ níwájú.

21. Dafidi ti wí pé, “Ṣé lásán ni mo dáàbò bo agbo ẹran Nabali ninu aṣálẹ̀, tí kò sí ohun ìní rẹ̀ kan tí ó sọnù. Ṣé bí ó ti yẹ kí ó fi ibi san ire fún mi nìyí.

22. Kí Ọlọrun pa mí bí mo bá fi ẹnikẹ́ni sílẹ̀ láìpa ninu àwọn eniyan Nabali títí di òwúrọ̀ ọ̀la.”

23. Nígbà tí Abigaili rí Dafidi, ó sọ̀kalẹ̀ kíákíá, ó wólẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀ lẹ́bàá

24. ẹsẹ̀ Dafidi, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ oluwa mi, gbọ́ ti èmi iranṣẹbinrin rẹ, kí o sì jẹ́ kí n ru ẹ̀bi àṣìṣe Nabali.

25. Jọ̀wọ́ má ṣe ka aláìmòye yìí sí, nítorí Nabali ni orúkọ rẹ̀, bí orúkọ rẹ̀ tí ń jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìwà rẹ̀ rí. Oluwa mi, n kò rí àwọn iranṣẹ rẹ nígbà tí wọ́n wá.

26. OLUWA tìkararẹ̀ ni ó ti ká ọ lọ́wọ́ kò láti má ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ ati láti má gbẹ̀san. Nisinsinyii, oluwa mi, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ ati àwọn tí wọn ń ro ibi sí ọ yóo dàbí Nabali.

27. Jọ̀wọ́ gba ẹ̀bùn tí èmi iranṣẹbinrin rẹ mú wá fún ọ kí o sì fi fún àwọn ọkunrin tí wọ́n tẹ̀lé ọ.

28. Jọ̀wọ́ dáríjì mí fún gbogbo àìṣedéédé mi. Dájúdájú OLUWA yóo jẹ́ kí o jọba ati àwọn ọmọ rẹ pẹlu. Nítorí pé ogun OLUWA ni ò ń jà, o kò sì hùwà ibi kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

29. Bí ẹnikẹ́ni bá sì ń gbèrò láti ṣe ọ́ ní ibi tabi láti pa ọ́, OLUWA yóo dáàbò bò ọ́ bí eniyan ti ń dáàbò bo ohun ìní olówó iyebíye. Ṣugbọn àwọn ọ̀tá rẹ ni a óo parun.

30. Nígbà tí OLUWA bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tí ó sì fi ọ́ jọba ní Israẹli,

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 25