Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 22:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Dafidi sá kúrò ní ìlú Gati, lọ sinu ihò òkúta kan lẹ́bàá Adulamu. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ ati ìdílé baba rẹ̀ gbọ́, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

2. Gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ìpọ́njú, ati àwọn tí wọ́n jẹ gbèsè ati àwọn tí wọ́n wà ninu ìbànújẹ́ sá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ irinwo (400) ọkunrin, ó sì jẹ́ olórí wọn.

3. Dafidi kúrò níbẹ̀ lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Moabu, ó sọ fún ọba Moabu pé, “Jọ̀wọ́ jẹ́ kí baba ati ìyá mi dúró lọ́dọ̀ rẹ títí tí n óo fi mọ ohun tí Ọlọrun yóo ṣe fún mi.”

4. Dafidi fi àwọn òbí rẹ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ ọba Moabu, wọ́n sì wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí Dafidi wà ní ìpamọ́.

5. Wolii Gadi sọ fún Dafidi pé, “Má dúró níbi ìpamọ́ yìí mọ́, múra, kí o lọ sí ilẹ̀ Juda.” Dafidi bá lọ sí igbó Hereti.

6. Nígbà tí Saulu jókòó ní abẹ́ igi tamarisiki ní orí òkè kan ni Gibea, ọ̀kọ̀ rẹ̀ wà ní ọwọ́ rẹ̀, àwọn olórí ogun rẹ̀ sì dúró yí i ká, ó gbọ́ pé wọ́n rí Dafidi ati àwọn ọkunrin tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

7. Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ará Bẹnjamini, ṣé ọmọ Jese yìí yóo fún olukuluku yín ní oko ati ọgbà àjàrà? Ṣé yóo sì fi olukuluku yín ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀?

8. Ṣé nítorí náà ni ẹ ṣe gbìmọ̀ burúkú sí mi, tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò fi sọ fún mi pé ọmọ mi bá ọmọ Jese dá majẹmu. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò sì káàánú mi láàrin yín, kí ó sì sọ fún mi pé, ọmọ mi ń ran iranṣẹ mi lọ́wọ́ láti ba dè mí, bí ọ̀rọ̀ ti rí lónìí yìí.”

9. Doegi ará Edomu, tí ó dúró láàrin àwọn olórí ogun Saulu dáhùn pé, “Mo rí Dafidi nígbà tí ó lọ sọ́dọ̀ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ní Nobu.

10. Ahimeleki bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA, lẹ́yìn náà ó fún Dafidi ní oúnjẹ ati idà Goliati, ará Filistia.”

11. Nítorí náà Saulu ọba ranṣẹ pe Ahimeleki ati gbogbo ìdílé rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ alufaa ní Nobu, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀.

12. Saulu ní, “Gbọ́ mi! Ìwọ ọmọ Ahitubu.”Ó dáhùn pé, “Mò ń gbọ́, oluwa mi.”

13. Saulu bi í pé, “Kí ló dé tí ìwọ ati ọmọ Jese fi gbìmọ̀ burúkú sí mi? Tí o fún un ní oúnjẹ ati idà, tí o sì tún bá a ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ Ọlọrun. Dafidi ti lòdì sí mi báyìí, ó sì ti ba dè mí, láti pa mí.”

14. Ahimeleki dáhùn pé, “Ta ló jẹ́ olóòótọ́ bíi Dafidi láàrin gbogbo àwọn olórí ogun rẹ? Ṣebí àna rẹ ni, ó sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun tí wọn ń ṣọ́ ọ ati eniyan pataki ninu ilé rẹ.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 22