Ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ará Bẹnjamini, ṣé ọmọ Jese yìí yóo fún olukuluku yín ní oko ati ọgbà àjàrà? Ṣé yóo sì fi olukuluku yín ṣe olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀?