Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 14:39-51 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Mo fi OLUWA alààyè tí ó fún Israẹli ní ìṣẹ́gun búra pé, pípa ni a óo pa ẹni tí ó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, kì báà jẹ́ Jonatani ọmọ mi.” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá a lóhùn ninu wọn.

40. Saulu bá wí fún gbogbo Israẹli pé, “Gbogbo yín, ẹ dúró ní apá kan, èmi ati Jonatani, ọmọ mi, yóo dúró ní apá keji.”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ.”

41. Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu,

42. Saulu ní, “Ẹ ṣẹ́ gègé láàrin èmi ati Jonatani, ọmọ mi.” Gègé bá mú Jonatani.

43. Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé kí ó sọ ohun tí ó ṣe fún òun.Jonatani dá a lóhùn pé, “Mo ti ọ̀pá tí mo mú lọ́wọ́ bọ inú oyin, mo sì lá a. Èmi nìyí, mo ṣetán láti kú.”

44. Saulu dá a lóhùn pé, “Láì sí àní àní, pípa ni wọn yóo pa ọ́; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, kí Ọlọrun lù mí pa.”

45. Nígbà náà ni àwọn eniyan wí fún Saulu pé, “Ṣé a óo pa Jonatani ni, ẹni tí ó ti ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli? Kí á má rí i. Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, ẹyọ irun orí rẹ̀ kan kò ní bọ́ sílẹ̀. Agbára Ọlọrun ni ó fi ṣe ohun tí ó ṣe lónìí.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan náà ṣe gba Jonatani kalẹ̀, tí wọn kò sì jẹ́ kí wọ́n pa á.

46. Lẹ́yìn èyí, Saulu kò lépa àwọn ará Filistia mọ́. Àwọn Filistini sì pada lọ sí agbègbè wọn.

47. Lẹ́yìn tí Saulu ti di ọba Israẹli tán, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ọ̀tá tí wọ́n yí i ká jagun; àwọn bíi: Moabu, Amoni, ati Edomu, ọba ilẹ̀ Soba, ati ti ilẹ̀ Filistini. Ní gbogbo ibi tí ó ti jagun ni ó ti pa wọ́n ní ìpakúpa.

48. Ó jagun gẹ́gẹ́ bí akikanju, ó ṣẹgun àwọn ará Amaleki. Ó sì gba Israẹli kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn tí wọn ń fi ogun kó wọn.

49. Àwọn ọmọ Saulu lọkunrin ni Jonatani, Iṣifi, ati Malikiṣua. Orúkọ ọmọbinrin rẹ̀ àgbà ni Merabu, ti èyí àbúrò ni Mikali.

50. Ahinoamu ọmọ Ahimaasi ni aya Saulu. Abineri ọmọ Neri, arakunrin baba Saulu, sì ni balogun rẹ̀.

51. Kiṣi ni baba Saulu. Neri, baba Abineri jẹ́ ọmọ Abieli.

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 14