Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 14:34-43 BIBELI MIMỌ (BM)

34. Ó tún pàṣẹ pé, “Ẹ lọ sí ààrin àwọn eniyan, kí ẹ sì wí fún wọn pé, kí wọ́n kó mààlúù wọn ati aguntan wọn wá síhìn-ín. Níhìn-ín ni kí wọ́n ti pa wọ́n, kí wọ́n sì jẹ wọ́n. Wọn kò gbọdọ̀ jẹ ẹran tẹ̀jẹ̀tẹ̀jẹ̀, kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA.” Nítorí náà, gbogbo wọn kó mààlúù wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Saulu ní alẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n sì pa wọ́n níbẹ̀.

35. Saulu bá tẹ́ pẹpẹ kan fún OLUWA. Pẹpẹ yìí ni pẹpẹ kinni tí Saulu tẹ́ fún OLUWA.

36. Saulu wí fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ kọlu àwọn ará Filistia ní òru kí á kó ẹrù wọn, kí á sì pa gbogbo wọn títí ilẹ̀ yóo fi mọ́ láì dá ẹnikẹ́ni sí.”Àwọn eniyan náà dá a lóhùn pé, “Ṣe èyí tí ó bá dára lójú rẹ.”Ṣugbọn alufaa wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́kọ́ bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun ná.”

37. Saulu bá bèèrè lọ́wọ́ Ọlọrun pé, “Ṣé kí n lọ kọlu àwọn ará Filistia? Ṣé o óo fún Israẹli ní ìṣẹ́gun?” Ṣugbọn Ọlọrun kò dá a lóhùn ní ọjọ́ náà.

38. Saulu bá pe gbogbo olórí àwọn eniyan náà jọ, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí á wádìí ohun tí ó fa ẹ̀ṣẹ̀ òní.

39. Mo fi OLUWA alààyè tí ó fún Israẹli ní ìṣẹ́gun búra pé, pípa ni a óo pa ẹni tí ó bá jẹ̀bi ọ̀rọ̀ yìí, kì báà jẹ́ Jonatani ọmọ mi.” Ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò dá a lóhùn ninu wọn.

40. Saulu bá wí fún gbogbo Israẹli pé, “Gbogbo yín, ẹ dúró ní apá kan, èmi ati Jonatani, ọmọ mi, yóo dúró ní apá keji.”Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ.”

41. Saulu bá ní, “OLUWA Ọlọrun Israẹli, kí ló dé tí o kò fi dá iranṣẹ rẹ lóhùn lónìí? OLUWA Ọlọrun Israẹli, bí ó bá jẹ́ pé èmi tabi Jonatani ni a jẹ̀bi, fi Urimu dáhùn. Ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé àwọn eniyan rẹ ni wọ́n ṣẹ̀, fi Tumimu dáhùn.” Urimu bá mú Jonatani ati Saulu,

42. Saulu ní, “Ẹ ṣẹ́ gègé láàrin èmi ati Jonatani, ọmọ mi.” Gègé bá mú Jonatani.

43. Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé kí ó sọ ohun tí ó ṣe fún òun.Jonatani dá a lóhùn pé, “Mo ti ọ̀pá tí mo mú lọ́wọ́ bọ inú oyin, mo sì lá a. Èmi nìyí, mo ṣetán láti kú.”

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 14