Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Kinni 12:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn náà, Samuẹli wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Mo ti ṣe ohun tí ẹ ní kí n ṣe. Mo ti fi ẹnìkan jọba lórí yín.

2. Nisinsinyii, ọba ni yóo máa ṣe olórí yín. Ní tèmi, mo ti dàgbà, ogbó sì ti dé sí mi. Àwọn ọmọ mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ yín. Láti ìgbà èwe mi ni mo ti jẹ́ olórí fun yín títí di àkókò yìí.

3. Èmi nìyí níwájú yín yìí, bí mo bá ti ṣe nǹkankan tí kò tọ́, ẹ fi ẹ̀sùn kàn mí níwájú OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀. Ǹjẹ́ mo gba mààlúù ẹnikẹ́ni ninu yín rí? Àbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ta ni mo gbà rí? Ta ni mo rẹ́ jẹ rí? Tabi ta ni mo ni lára rí? Ǹjẹ́ mo gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí? Bí mo bá ti ṣe èyíkéyìí ninu àwọn nǹkan wọnyi rí, mo ṣetán láti san ohun tí mo gbà pada.”

4. Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Rárá o, o kò rẹ́ wa jẹ rí, o kò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí.”

5. Samuẹli dáhùn pé, “OLUWA ati ọba, ẹni àmì òróró rẹ̀ ni ẹlẹ́rìí lónìí pé, ẹ gbà pé ọwọ́ mi mọ́ patapata.”Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA ni ẹlẹri wa.”

6. Samuẹli tún sọ fún wọn pé, “OLUWA tí ó yan Mose ati Aaroni, tí ó kó àwọn baba ńlá yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti ni ẹlẹ́rìí.

7. Ẹ dúró jẹ́ẹ́, n óo sì fi ẹ̀sùn kàn yín níwájú OLUWA n óo ran yín létí gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe láti gba àwọn baba ńlá yín kalẹ̀.

8. Nígbà tí Jakọbu ati ìdílé rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti, tí àwọn ará Ijipti ń ni wọ́n lára, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́, OLUWA sì rán Mose ati Aaroni, wọ́n kó wọn jáde kúrò ní Ijipti. Ó sì mú kí wọ́n máa gbé orí ilẹ̀ yìí.

9. Ṣugbọn wọ́n gbàgbé OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n jagun, OLUWA sì fi wọ́n lé Sisera, olórí ogun Jabini ọba Hasori lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ati ọba Moabu náà sì ṣẹgun wọn.

10. Lẹ́yìn náà, àwọn baba ńlá yín kígbe pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́. Wọ́n ní, ‘A ti ṣẹ̀, nítorí pé a ti kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń sin oriṣa Baali, ati ti Aṣitarotu. Nisinsinyii, gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, a óo sì máa sìn ọ́.’

Ka pipe ipin Samuẹli Kinni 12