Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 21:6-19 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Nítorí náà, fún wa ní meje ninu àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, kí á lè so wọ́n kọ́ níwájú OLUWA ní Gibea, ní orí òkè OLUWA.”Dafidi dáhùn pé, “N óo kó wọn lé yín lọ́wọ́.”

7. Ṣugbọn nítorí majẹmu tí ó wà láàrin Dafidi ati Jonatani, Dafidi kò fi ọwọ́ kan Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, ọmọ Saulu.

8. Ṣugbọn ó mú Arimoni ati Mẹfiboṣẹti àwọn ọmọkunrin mejeeji tí Risipa, ọmọ Aya, bí fún Saulu; ó sì tún mú àwọn ọmọ marun-un tí Merabu, ọmọbinrin Saulu, bí fún Adirieli ọmọ Basilai ará Mehola.

9. Dafidi kó wọn lé àwọn ará Gibeoni lọ́wọ́, àwọn ará Gibeoni sì so wọ́n kọ́ sórí igi, lórí òkè níwájú OLUWA, àwọn mejeeje sì kú papọ̀. Àkókò tí wọ́n kú yìí jẹ́ àkókò ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè ọkà baali nígbà tí àkókò ìrúwé fẹ́rẹ̀ kásẹ̀ nílẹ̀.

10. Risipa, ọmọbinrin Aya, fi aṣọ ọ̀fọ̀ pa àtíbàbà fún ara rẹ̀ lórí òkúta, níbi tí òkú àwọn tí wọ́n pa wà. Ó wà níbẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ìkórè, títí di àkókò tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ní ojúmọmọ, kò jẹ́ kí àwọn ẹyẹ jẹ wọ́n ní ọ̀sán, kò sì jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú fọwọ́ kàn wọ́n lóru.

11. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí Risipa, ọmọ Aya, obinrin Saulu ṣe,

12. ó lọ kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀, tí ó wà lọ́dọ̀ àwọn ará Jabeṣi-Gileadi. (Àwọn ará Jabeṣi ti jí àwọn egungun náà kó kúrò ní ìta gbangba, ní ààrin ìlú ní Beti Ṣani, níbi tí àwọn ará Filistia so wọ́n kọ́ sí, ní ọjọ́ tí wọ́n pa wọ́n ní òkè Giliboa.)

13. Láti ibẹ̀ ni ó ti kó egungun Saulu, ati ti Jonatani, ọmọ rẹ̀. Wọ́n sì kó egungun àwọn mejeeje tí wọ́n so kọ́ pẹlu.

14. Wọ́n sin egungun Saulu, ati ti Jonatani, sinu ibojì Kiṣi, baba rẹ̀, ní Sela ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Bẹnjamini. Gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni wọ́n ṣe. Lẹ́yìn náà, ni Ọlọrun gbọ́ adura tí wọ́n ń gbà fún ilẹ̀ náà.

15. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ará Filistia ati àwọn ọmọ Israẹli. Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì lọ bá àwọn ará Filistia jagun. Bí wọ́n ti ń jà, àárẹ̀ mú Dafidi.

16. Òmìrán kan tí ń jẹ́ Iṣibibenobu, gbèrò láti pa Dafidi. Ọ̀kọ̀ Iṣibibenobu yìí wọ̀n tó ọọdunrun ṣekeli idẹ, ó sì so idà tuntun mọ́ ẹ̀gbẹ́.

17. Ṣugbọn Abiṣai, ọmọ Seruaya, sáré wá láti ran Dafidi lọ́wọ́, ó kọlu òmìrán náà, ó sì pa á. Láti ìgbà náà ni àwọn ọmọ ogun Dafidi ti búra fún un pé, “A kò ní jẹ́ kí o bá wa lọ sí ojú ogun mọ́ kí á má baà pàdánù rẹ, nítorí pé ìwọ ni ìrètí Israẹli.”

18. Lẹ́yìn èyí, ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia, ní Gobu, ninu ogun yìí ni Sibekai ará Huṣa ti pa Safu, ọ̀kan ninu àwọn ìran òmìrán.

19. Ogun mìíràn tún bẹ́ sílẹ̀ pẹlu àwọn ará Filistia kan náà, ní Gobu. Ninu ogun yìí ni Elihanani ọmọ Jaareoregimu, ará Bẹtilẹhẹmu, ti pa Goliati, ará Giti, ẹni tí ọ̀pá ọ̀kọ̀ rẹ̀ nípọn tó igi òfì tí àwọn obinrin fi máa ń hun aṣọ.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 21