Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 20:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní,“Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi,a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese.Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.”

2. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu.

3. Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú.

4. Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.”

5. Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá.

6. Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.”

7. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba.

8. Nígbà tí wọ́n dé ibi òkúta ńlá kan, tí ó wà ní Gibeoni, Amasa lọ pàdé wọn. Ẹ̀wù ọmọ ogun ni Joabu wọ̀; ó sán ìgbànú kan, idà rẹ̀ sì wà ninu àkọ̀ lára ìgbànú tí ó ti sán mọ́ ìbàdí. Bí Joabu ti rìn siwaju bẹ́ẹ̀ ni idà yìí bọ́ sílẹ̀.

9. Ó bá bèèrè lọ́wọ́ Amasa pé, “Ṣé alaafia ni, arakunrin mi?” Ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbá Amasa ní irùngbọ̀n mú, bí ẹni pé ó fẹ́ fi ẹnu kò ó ní ẹnu.

10. Amasa kò fura rárá pé idà wà ní ọwọ́ Joabu. Joabu bá gún un ní idà níkùn, gbogbo ìfun rẹ̀ tú jáde. Amasa kú lẹsẹkẹsẹ, láì jẹ́ pé Joabu tún gún un ní idà lẹẹkeji.Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ bá ń lépa Ṣeba lọ.

11. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Joabu dúró ti òkú Amasa, ó sì ń kígbe pé, “Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe ti Joabu ati ti Dafidi tẹ̀lé Joabu.”

12. Òkú Amasa, tí ẹ̀jẹ̀ ti bò, wà ní ojú ọ̀nà gbangba, ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọjá, tí ó bá rí i ń dúró. Nígbà tí ọkunrin tí ó dúró ti òkú náà rí i pé gbogbo eniyan ní ń dúró, ó wọ́ òkú náà kúrò lójú ọ̀nà, sinu igbó, ó sì fi aṣọ bò ó.

13. Nígbà tí ó wọ́ ọ kúrò lójú ọ̀nà tán, gbogbo àwọn eniyan bẹ̀rẹ̀ sí sá tẹ̀lé Joabu, wọ́n ń lépa Ṣeba lọ.

14. Ṣeba la ilẹ̀ gbogbo ẹ̀yà Israẹli já, ó lọ sí ìlú Abeli ti Beti Maaka. Gbogbo àwọn ará Bikiri bá péjọ, wọ́n sì tẹ̀lé e wọnú ìlú náà.

15. Àwọn ọmọ ogun Joabu bá lọ dó ti ìlú náà, wọ́n fi erùpẹ̀ mọ òkítì gíga sára odi rẹ̀ lóde, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ́ odi náà lábẹ́, wọ́n fẹ́ wó o lulẹ̀.

16. Obinrin ọlọ́gbọ́n kan wà ninu ìlú náà, tí ó kígbe láti orí odi, ó ní, “Ẹ tẹ́tí, ẹ gbọ́! Ẹ sọ fún Joabu kí ó wá gbọ́! Mo ní ọ̀rọ̀ kan tí mo fẹ́ bá a sọ.”

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 20