Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Samuẹli Keji 19:4-17 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ọba dọwọ́ bojú, ó ń sọkún, ó sì ń kígbe sókè pé, “Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi!”

5. Joabu bá wọlé tọ ọba lọ, ó wí fún un pé, “O ti dójúti àwọn ọmọ ogun rẹ lónìí, àwọn tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ là, ati ẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ, ati ti àwọn aya rẹ, ati àwọn obinrin rẹ;

6. nítorí pé o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. O ti fihàn gbangba pé, àwọn ọ̀gágun ati ọmọ ogun rẹ kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ. Mo ti rí i gbangba lónìí pé, ìbá dùn mọ́ ọ ninu, bí gbogbo wa tilẹ̀ kú, tí Absalomu sì wà láàyè.

7. Yára dìde, kí o lọ tu àwọn ọmọ ogun ninu; nítorí pé mo fi OLUWA búra pé, bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní ku ẹnìkan ninu wọn pẹlu rẹ ní òwúrọ̀ ọ̀la. Èyí yóo wá burú ju gbogbo ibi tí ó ti bá ọ láti ìgbà èwe rẹ títí di òní lọ.”

8. Ọba bá dìde, ó lọ jókòó lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ibodè. Àwọn eniyan rẹ̀ gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, gbogbo wọn bá wá rọ̀gbà yí i ká.Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá, olukuluku ti pada sí ilé rẹ̀.

9. Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu.

10. A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.”

11. Ìròyìn ohun tí àwọn eniyan Israẹli ń wí kan Dafidi ọba lára. Dafidi ọba ranṣẹ sí àwọn alufaa mejeeji: Sadoku, ati Abiatari, láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà Juda pé, “Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀?

12. Ṣebí ìbátan ọba ni yín, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni yín? Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀.”

13. Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀.

14. Ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ yìí, mú kí àwọn eniyan Juda fara mọ́ ọn, wọ́n sì ranṣẹ sí i pé kí ó pada pẹlu gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.

15. Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani.

16. Ní àkókò yìí kan náà, Ṣimei, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini, láti ìlú Bahurimu, sáré lọ sí odò Jọdani láti pàdé Dafidi ọba pẹlu àwọn eniyan Juda.

17. Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 19