Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nehemaya 4:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Sanbalati gbọ́ pé a ti ń kọ́ odi náà, inú bíi gidigidi, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Juu.

2. Ó sọ lójú àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Samaria pé, “Kí ni àwọn Juu aláìlera wọnyi ń ṣé? Ṣé wọn yóo tún ìlú wọn kọ́ ni? Ṣé wọn yóo tún máa rúbọ ni? Ṣé ọjọ́ kan ṣoṣo ni wọ́n fẹ́ parí rẹ̀ ni? Ṣé wọn yóo lè yọ àwọn òkúta kúrò ninu àlàpà tí wọ́n wà, kí wọn sì fi òkúta tí ó ti jóná gbẹ́ òkúta ìkọ́lé?”

3. Tobaya ará Amoni náà sì fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, bí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun orí ohun tí wọ́n mọ, tí wọn ń pè ní odi olókùúta, wíwó ni yóo wó o lulẹ̀!”

4. Mo bá gbadura pé, “Gbọ́, Ọlọrun wa, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn wa. Yí ẹ̀gàn wọn pada lé wọn lórí, kí o sì fi wọ́n lé alágbèédá lọ́wọ́ ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ.

5. Má mójú fo àìdára wọn, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò ninu àkọsílẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ, nítorí pé wọ́n ti mú ọ bínú níwájú àwọn tí wọn ń mọ odi.”

6. Bẹ́ẹ̀ ni, à ń mọ odi náà, a mọ ọ́n já ara wọn yípo, ó sì ga dé ìdajì ibi tí ó yẹ kí ó ga dé, nítorí pé àwọn eniyan náà ṣiṣẹ́ tọkàntọkàn.

7. Ṣugbọn nígbà tí Sanbalati ati Tobaya ati àwọn ará Arabu, ati àwọn ará Amoni, ati àwọn ará Aṣidodu, gbọ́ pé a ti ń ṣe àtúnṣe àwọn odi Jerusalẹmu ati pé a ti ń dí àwọn ihò ibẹ̀, inú bí wọn gidigidi.

8. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí dìtẹ̀ láti wá gbógun ti Jerusalẹmu kí wọ́n lè dá rúkèrúdò sílẹ̀.

9. Ṣugbọn a gbadura sí Ọlọrun wa, a sì yan àwọn olùṣọ́ láti máa ṣọ́ ibẹ̀ tọ̀sán-tòru.

10. Àwọn ará Juda bẹ̀rẹ̀ sí kọrin pé,“Agbára àwa tí à ń ṣe iṣẹ́ ń dín kù,iṣẹ́ sì tún pọ̀ nílẹ̀;ǹjẹ́ a ó lè mọ odi náà mọ́ báyìí?”

11. Àwọn ọ̀tá wa sì wí pé, “Wọn kò ní mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní rí wa títí tí a óo fi dé ọ̀dọ̀ wọn, tí a óo pa wọ́n, tí iṣẹ́ náà yóo sì dúró.”

12. Ṣugbọn àwọn Juu tí wọn ń gbé ààrin wọn wá sí ọ̀dọ̀ wa ní ọpọlọpọ ìgbà, wọ́n sì sọ fún wa pé, “Láti gbogbo ilẹ̀ wọn ni wọn yóo ti dìde ogun sí wa.”

13. Nítorí náà mo fi àwọn eniyan ṣọ́ gbogbo ibi tí odi ìlú bá ti gba ibi tí ilẹ̀ ti dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, mo yan olukuluku ní ìdílé ìdílé, wọ́n ń ṣọ́ odi ní agbègbè wọn pẹlu idà, ọ̀kọ̀, ati ọrun wọn.

14. Mo dìde, mo wò yíká, mo bá sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè, ati àwọn eniyan yòókù pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín. Ẹ ranti OLUWA tí ó tóbi tí ó sì bani lẹ́rù, kí ẹ sì jà fún àwọn arakunrin yín, ati àwọn ọmọkunrin yín, àwọn ọmọbinrin yín, ati àwọn iyawo yín, ati àwọn ilé yín.”

Ka pipe ipin Nehemaya 4