Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Lefitiku 5:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Bí ẹnìkan bá dẹ́ṣẹ̀, nípa pé ó gbọ́ tí wọn ń kéde láàrin àwùjọ pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ̀ nípa ọ̀ràn kan jáde wá láti jẹ́rìí, bí ó bá mọ ohunkohun nípa ọ̀ràn náà, kì báà jẹ́ pé ó rí i ni, tabi wọ́n sọ ohunkohun fún un nípa rẹ̀ ni, tí ó bá dákẹ́, tí kò sọ ohunkohun, yóo jẹ̀bi.

2. “Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ọwọ́ kan ohunkohun tí ó jẹ́ aláìmọ́, kì báà jẹ́ òkú ẹranko tí ó jẹ́ aláìmọ́ ni, tabi òkú ẹran ọ̀sìn tí ó jẹ́ aláìmọ́, tabi òkú ohunkohun tí ń fàyà fà nílẹ̀ tí ó jẹ́ aláìmọ́, bí kò tilẹ̀ mọ̀, sibẹ òun pàápàá di aláìmọ́, ó sì jẹ̀bi.

3. “Tabi bí ó bá fara kan ohun aláìmọ́ kan lára eniyan, ohun yòówù kí ohun náà jẹ́, ó ti sọ ẹni náà di aláìmọ́, bí irú ohun bẹ́ẹ̀ bá pamọ́ fún un, ìgbà yòówù tí ó bá mọ̀, ó jẹ̀bi.

4. “Tabi bí ẹnikẹ́ni bá fi ẹnu ara rẹ̀ búra láìronú, kì báà jẹ́ láti ṣe ibi ni, tabi láti ṣe rere, irú ìbúra kíbùúra tí eniyan lè ṣe láìmọ̀, nígbà tí ó bá mọ̀, ó di ẹlẹ́bi.

5. “Nígbà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ̀bi ọ̀kankan ninu àwọn ohun tí a ti dárúkọ wọnyi, kí ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá,

6. kí ó sì mú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ OLUWA fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá. Kí ó mú abo ọ̀dọ́ aguntan, tabi ti ewúrẹ́ wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, alufaa yóo sì ṣe ètùtù fún un nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

7. “Bí kò bá ní agbára láti mú ọ̀dọ́ aguntan wá, ohun tí ó tún lè mú tọ OLUWA wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji, ọ̀kan fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ekeji fún ẹbọ sísun.

Ka pipe ipin Lefitiku 5