Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 6:19-36 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Sibẹsibẹ, jọ̀wọ́ fetí sí adura ati ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ. OLUWA Ọlọrun mi, gbọ́ igbe èmi iranṣẹ rẹ, ati adura tí mò ń gbà níwájú rẹ.

20. Máa bojútó ilé yìí tọ̀sán-tòru. O ti sọ pé ibẹ̀ ni àwọn eniyan yóo ti máa jọ́sìn ní orúkọ rẹ. Jọ̀wọ́ máa gbọ́ adura tí èmi iranṣẹ rẹ bá gbà nígbà tí mo bá kọjú sí ilé yìí.

21. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ èmi iranṣẹ rẹ, ati ti Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ibí yìí láti gbadura. Gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láti ibùgbé rẹ ní ọ̀run, kí o sì dáríjì wá.

22. “Bí ẹnìkan bá ṣẹ aládùúgbò rẹ̀, tí a sì mú un wá kí ó wá búra níwájú pẹpẹ rẹ ninu ilé yìí,

23. OLUWA, gbọ́ láti ọ̀run, kí o ṣe ìdájọ́ àwọn iranṣẹ rẹ. Jẹ ẹni tí ó bá ṣẹ̀ níyà bí ó ti tọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, kí o dá ẹni tí kò ṣẹ̀ láre gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀.

24. “Nígbà tí àwọn ọ̀tá bá ṣẹgun àwọn eniyan rẹ lójú ogun nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ ọ́, ṣugbọn bí wọ́n bá ronupiwada, tí wọ́n ranti orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura, tí wọ́n sì bẹ̀ ọ́ ninu ilé yìí,

25. jọ̀wọ́ gbọ́ láti ọ̀run, kí o dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, jì wọ́n, kí o sì mú wọn pada sórí ilẹ̀ tí o ti fún àwọn ati àwọn baba wọn.

26. “Nígbà tí òjò bá kọ̀ tí kò rọ̀, nítorí pé àwọn eniyan rẹ ṣẹ̀, bí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, tí wọ́n jẹ́wọ́ orúkọ rẹ, tí wọ́n yipada kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nítorí pé o ti jẹ wọ́n níyà,

27. jọ̀wọ́, gbọ́ láti ọ̀run, kí o sì dáríjì àwọn eniyan Israẹli, àwọn iranṣẹ rẹ. Tọ́ wọn sí ọ̀nà tí wọn yóo máa tọ̀, kí o sì jẹ́ kí òjò rọ̀ sí ilẹ̀ tí o fún àwọn eniyan rẹ gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

28. “Nígbàkúùgbà tí ìyàn bá mú ní ilẹ̀ yìí, tabi tí àjàkálẹ̀ àrùn bá bẹ́ sílẹ̀, tabi ọ̀gbẹlẹ̀, tabi ìrẹ̀dànù ohun ọ̀gbìn, tabi eṣú, tabi kòkòrò tíí máa jẹ ohun ọ̀gbìn; tabi tí àwọn ọ̀tá bá gbógun ti èyíkéyìí ninu àwọn ìlú wọn, irú ìyọnu tabi àìsàn yòówù tí ó lè jẹ́,

29. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan, tabi ti gbogbo Israẹli, eniyan rẹ, lẹ́yìn tí olukuluku ti mọ ìṣòro ati ìbànújẹ́ rẹ̀, bí wọ́n bá gbé ọwọ́ adura wọn sókè sí ìhà ilé yìí,

30. jọ̀wọ́, gbọ́ láti ilé rẹ ní ọ̀run, dáríjì wọ́n, kí o sì ṣe ẹ̀tọ́ fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀, nítorí ìwọ nìkan ni o mọ ọkàn ọmọ eniyan.

31. Kí àwọn eniyan rẹ lè máa bẹ̀rù rẹ, kí wọ́n sì máa rìn ní ọ̀nà rẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé wọn lórí ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wa.

32. “Bákan náà, nígbà tí àwọn àjèjì, tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, bá ti ọ̀nà jíjìn wá, láti gbadura sí ìhà ilé yìí, nítorí orúkọ ńlá rẹ, ati iṣẹ́ ńlá, ati agbára rẹ,

33. gbọ́ láti ibùgbé rẹ lọ́run; kí o sì ṣe gbogbo ohun tí àjèjì náà bá ń tọrọ lọ́dọ̀ rẹ, kí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà láyé lè mọ orúkọ rẹ, kí wọ́n sì máa bẹ̀rù rẹ, bí àwọn eniyan rẹ tí ń ṣe, kí wọ́n lè mọ̀ pé ilé ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ, ni ilé tí mo kọ́ yìí.

34. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ sójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn, láti lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà, tí wọ́n bá kọjú sí ìhà ìlú tí o ti yàn yìí ati sí ìhà ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ yìí,

35. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run, kí o sì jà fún wọn.

36. “Bí wọ́n bá ṣẹ̀ ọ́ (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í ṣẹ̀), tí inú bá bí ọ sí wọn, tí o sì mú kí àwọn ọ̀tá wọn ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ọ̀nà jíjìn tabi nítòsí,

Ka pipe ipin Kronika Keji 6