Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Kronika Keji 34:18-29 BIBELI MIMỌ (BM)

18. ati pé, “Hilikaya, alufaa, fún mi ní ìwé kan.” Ṣafani sì kà á níwájú ọba.

19. Nígbà tí ọba gbọ́ ohun tí ó wà ninu ìwé òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya láti fi ìbẹ̀rù ati ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn.

20. Ó pàṣẹ fún Hilikaya, Ahikamu, ọmọ Ṣafani, Abidoni, ọmọ Mika, ati Ṣafani, akọ̀wé, ati Asaya, iranṣẹ ọba, pé,

21. “Ẹ tọ Ọlọrun lọ fún èmi ati àwọn eniyan tí wọ́n kù ní Juda ati ní Israẹli, ẹ ṣe ìwádìí ohun tí a kọ sinu ìwé náà; nítorí pé àwọn baba ńlá wa tàpá sí ọ̀rọ̀ OLUWA, wọn kò sì ṣe ohun tí a kọ sinu ìwé yìí ni OLUWA ṣe bínú sí wa lọpọlọpọ.”

22. Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, Hilikaya ati àwọn tí wọ́n tẹ̀lé e, lọ sọ́dọ̀ Hulida, wolii obinrin, iyawo Ṣalumu, ọmọ Tokihati, ọmọ Hasira tí ó jẹ́ alabojuto ibi tí wọn ń kó aṣọ pamọ́ sí ní ìhà keji Jerusalẹmu tí Hulida ń gbé. Wọ́n sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.

23. Ó bá dá wọn lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n sọ fun yín, kí ẹ sọ fún ẹni tí ó ran yín sí mi pé

24. òun OLUWA ní òun óo mú ibi wá sórí ibí yìí ati àwọn eniyan ibẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé tí a kà sí ọba Juda létí.

25. Nítorí pé wọ́n ti kọ òun OLUWA sílẹ̀, wọ́n sì ń sun turari sí àwọn oriṣa, kí wọ́n lè fi ìṣe wọn mú òun bínú; nítorí náà òun óo bínú sí ibí yìí, kò sí ẹni tí yóo lè dá ibinu òun dúró.

26. Ó ní kí ẹ sọ ohun tí ẹ ti gbọ́ fún ọba Juda tí ó ranṣẹ láti wá wádìí lọ́wọ́ OLUWA Ọlọrun pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní,

27. nítorí pé nígbà tí ó gbọ́ nípa ìyà tí n óo fi jẹ Jerusalẹmu ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀, ó ronupiwada, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì sọkún níwájú mi, mo sì ti gbọ́ adura rẹ̀.

28. Nítorí náà, ìdájọ́ tí mo ti pinnu sórí Jerusalẹmu kò ní ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ayé rẹ̀, ikú wọ́ọ́rọ́ ni yóo sì kú.”Àwọn eniyan náà bá pada lọ jíṣẹ́ fún ọba.

29. Lẹ́yìn náà, Josaya ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà Juda ati ti Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Kronika Keji 34