Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Joṣua 15:7-20 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli.

8. Ààlà náà tún lọ sí apá òkè, sí àfonífojì ọmọ Hinomu ní apá gúsù òkè àwọn ará Jebusi (tíí ṣe ìlú Jerusalẹmu). Ó tún lọ títí dé orí òkè náà, tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní òpin ìhà àríwá àfonífojì Refaimu.

9. Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.)

10. Ààlà náà tún yípo lọ sí ìwọ̀ oòrùn Baala, sí apá òkè Seiri, lọ sí apá ìhà àríwá òkè Jearimu (tí a tún ń pè ní Kesaloni), ó bá tún dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sí Beti Ṣemeṣi títí dé ìkọjá Timna.

11. Ó tún gba ti àwọn òkè tí ó wà ní ìhà àríwá Ekironi, ó wá yípo lọ sí Ṣikeroni. Lẹ́yìn náà, ó kọjá lọ sí òkè Baala títí dé Jabineeli, ó wá lọ parí sí Òkun Mẹditarenia.

12. Òkun yìí ni ààlà ilẹ̀ náà ní apá ìwọ̀ oòrùn.Òun ni ààlà ilẹ̀ àwọn ọmọ Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

13. Gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Joṣua, ó fún Kalebu ọmọ Jefune ní Heburoni gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀ ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Juda. Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba, (tí a tún ń pè ní ìlú Ariba), Ariba yìí ni baba Anaki.

14. Kalebu lé àwọn ìran Anaki mẹtẹẹta jáde níbẹ̀, àwọn ni ìran Ṣeṣai, ìran Ahimani, ati ìran Talimai.

15. Láti ibẹ̀ ó lọ gbógun ti àwọn ará ìlú Debiri. Orúkọ Debiri tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Seferi.

16. Kalebu ṣe ìlérí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣẹgun Kiriati Seferi tí ó sì gba ìlú náà ni òun yóo fún ní Akisa ọmọ òun, láti fi ṣe aya.

17. Otinieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, ni ó ṣẹgun ìlú náà. Kalebu bá fi Akisa ọmọ rẹ̀ fún un láti fi ṣe aya.

18. Nígbà tí Akisa dé ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ̀, ó rọ ọkọ rẹ̀ pé kí ó tọrọ ilẹ̀ kan lọ́wọ́ baba òun. Ní ọjọ́ kan, bí Akisa ti sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, baba rẹ̀ bi í pé, “Kí ni ò ń fẹ́?”

19. Akisa dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Fún mi ní ẹ̀bùn, níwọ̀n ìgbà tí o ti fún mi ní ilẹ̀ Nẹgẹbu, fún mi ní àwọn orísun omi pẹlu.” Kalebu bá fún un ní àwọn orísun omi tí wọ́n wà lókè ati àwọn tí wọ́n wà ní ìsàlẹ̀.

20. Èyí ni ilẹ̀ ẹ̀yà Juda gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn,

Ka pipe ipin Joṣua 15