Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jeremaya 44:12-22 BIBELI MIMỌ (BM)

12. N óo run gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní ilẹ̀ Juda tí wọ́n gbójú lé àtilọ máa gbé ilẹ̀ Ijipti, wọn kò ní ku ẹyọ kan ní ilẹ̀ Ijipti. Gbogbo wọn ni wọn óo parun láti orí àwọn mẹ̀kúnnù dé orí àwọn eniyan pataki pataki; ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n. Wọn yóo di ẹni ìfibú, ẹni àríbẹ̀rù, ẹni ègún ati ẹni ẹ̀sín.

13. N óo fìyà jẹ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, n óo fi ogun, ìyàn, ati àjàkálẹ̀ àrùn pa wọ́n run bí mo ṣe fi pa Jerusalẹmu run.

14. Ẹnikẹ́ni kò ní yè ninu àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ní Juda, tí wọ́n lọ fi ilẹ̀ Ijipti ṣe ilé; wọn kò ní sá àsálà, wọn kò sì ní yè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní pada sí ilẹ̀ Juda tí ọkàn wọn fẹ́ pada sí. Wọn kò ní pada, àfi àwọn bíi mélòó kan ni wọ́n óo sá àsálà.’ ”

15. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n mọ̀ pé àwọn iyawo wọn ń sun turari sí àwọn oriṣa ati àwọn obinrin tí wọ́n pọ̀ gbáà tí wọn wà nítòsí ibẹ̀, ati àwọn tí wọn ń gbé Patirosi ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n bá dá Jeremaya lóhùn,

16. wọ́n ní, “A kò ní fetí sì ọ̀rọ̀ tí ò ń bá wa sọ lórúkọ OLUWA.

17. Ṣugbọn a óo máa san gbogbo ẹ̀jẹ́ wa, a óo máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, oriṣa wa, a óo sì máa ta ohun mímu sílẹ̀, bí àwa ati àwọn baba ńlá wa, ati àwọn ọba wa ati àwọn olórí wa ti ṣe ní gbogbo ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu; nítorí pé nígbà náà à ń jẹ oúnjẹ ní àjẹyó, ó dára fún wa, ojú wa kò sì rí ibi.

18. Ṣugbọn láti ìgbà tí a ti dáwọ́ ati máa sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run dúró, tí a kò sì máa ta ohun mímu sílẹ̀ mọ́, ni a kò ti ní nǹkankan mọ́, tí ogun ati ìyàn sì fẹ́ẹ̀ pa wá tán.”

19. Àwọn obinrin bá tún dáhùn pé, “Nígbà tí à ń sun turari sí ọbabinrin ojú ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ ohun mímu sí i, ṣé àwọn ọkọ wa ni kò mọ̀ pé à ń ṣe àkàrà dídùn, tí à ń ṣe bí ère rẹ̀ fún un ni, ati pé à ń ta ohun mímu sílẹ̀ fún un?”

20. Jeremaya sọ fún gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n dá a lóhùn, lọkunrin ati lobinrin pé:

21. “Ṣebí OLUWA ranti turari tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín, ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati gbogbo àwọn eniyan ilẹ̀ náà sun ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu, ṣebí OLUWA ranti.

22. OLUWA kò lè farada ìwà burúkú tí ẹ̀ ń hù, ati àwọn nǹkan ìríra tí ẹ̀ ń ṣe, nítorí náà, ni ilẹ̀ yín ṣe di ahoro ati aṣálẹ̀, ati ilẹ̀ tí a fi ń gégùn-ún, tí kò ní olùgbé, títí di òní.

Ka pipe ipin Jeremaya 44