orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ire Israẹli eniyan mi pada, tí mo bá sì fẹ́ wò wọ́n sàn, kìkì ìwà ìbàjẹ́ Efuraimu ati ìwà ìkà Samaria ni mò ń rí; nítorí pé ìwà aiṣododo ni wọ́n ń hù. Àwọn olè ń fọ́lé, àwọn jàgùdà sì ń jalè ní ìgboro.

2. Ṣugbọn wọn kò rò ó pé mò ń ranti gbogbo ìwà burúkú àwọn. Ìwà burúkú wọn yí wọn ká, ẹ̀ṣẹ̀ wọn sì wà níwájú mi.”

Ọ̀tẹ̀ ní Ààfin

3. OLUWA wí pé, “Àwọn eniyan ń dá ọba ninu dùn, nípa ìwà ibi wọn, wọ́n ń mú àwọn ìjòyè lóríyá nípa ìwà ẹ̀tàn wọn.

4. Alágbèrè ni gbogbo wọn; wọ́n dàbí iná ààrò burẹdi tí ó gbóná, tí ẹni tí ń ṣe burẹdi kò koná mọ́, láti ìgbà tí ó ti po ìyẹ̀fun títí tí ìyẹ̀fun náà fi wú.

5. Ní ọjọ́ tí ọba ń ṣe àjọyọ̀, àwọn ìjòyè mu ọtí àmupara, títí tí ara wọn fi gbóná; ọba pàápàá darapọ̀ mọ́ àwọn ẹlẹ́yà.

6. Iná ọ̀tẹ̀ wọn ń jò bí iná ojú ààrò, inú wọn ń ru, ó ń jó bí iná ní gbogbo òru; ní òwúrọ̀, ó ń jó lálá bí ahọ́n iná.

7. “Gbogbo wọn gbóná bí ààrò, wọ́n pa àwọn olórí wọn, gbogbo ọba wọn ni wọ́n ti pa léraléra, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó ké pè mí.”

Israẹli ati Àwọn Orílẹ̀-Èdè

8. OLUWA ní, “Efuraimu darapọ̀ mọ́ àwọn eniyan tí wọ́n yí wọn ká, Efuraimu dàbí àkàrà tí kò jinná dénú.

9. Àwọn àjèjì ti gba agbára rẹ̀, sibẹsibẹ kò mọ̀; orí rẹ̀ kún fún ewú, sibẹsibẹ kò mọ̀.

10. Ìgbéraga àwọn ọmọ Israẹli ń takò wọ́n, sibẹsibẹ wọn kò pada sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn, tabi kí wọ́n tilẹ̀ wá a nítorí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe.

11. Efuraimu dàbí ẹyẹ àdàbà, ó jẹ́ òmùgọ̀ ati aláìlóye, ó ń pe Ijipti fún ìrànlọ́wọ́, o ń sá tọ Asiria lọ.

12. Ṣugbọn bí wọn tí ń lọ, n óo da àwọ̀n lé wọn lórí, n óo mú wọn bí ẹyẹ ojú ọ̀run; n óo sì jẹ wọ́n níyà fún ìwà burúkú wọn.

13. “Wọ́n gbé, nítorí pé wọ́n ti ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìparun yóo kọlù wọ́n, nítorí pé wọ́n ń bá mi ṣọ̀tẹ̀! Ǹ bá rà wọ́n pada, ṣugbọn wọ́n ń parọ́ mọ́ mi.

14. Wọ́n ń sọkún lórí ibùsùn wọn, ṣugbọn ẹkún tí wọn ń sun sí mi kò ti ọkàn wá; nítorí oúnjẹ ati ọtí waini ni wọ́n ṣe ń gbé ara ṣánlẹ̀; ọ̀tẹ̀ ni wọ́n ń bá mi ṣe.

15. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, èmi ni mo tọ́ wọn dàgbà, tí mo sì fún wọn lókun, sibẹsibẹ wọ́n ń gbèrò ibi sí mi.

16. Wọ́n yipada sí oriṣa Baali, wọ́n dàbí ọrun tí ó wọ́, idà ni a óo fi pa àwọn olórí wọn, nítorí ìsọkúsọ ẹnu wọn. Nítorí náà, wọn óo ṣẹ̀sín ní ilẹ̀ Ijipti.”