orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Asán ati ìbàjẹ́ ni gbogbo nǹkan tí Efuraimu ń ṣe látàárọ̀ dalẹ́. Wọ́n ń parọ́ kún irọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwà ipá wọn ń pọ̀ sí i. Wọ́n ń bá àwọn Asiria dá majẹmu, wọ́n sì ń ru òróró lọ sí ilẹ̀ Ijipti.”

2. OLUWA ní ẹjọ́ tí yóo bá àwọn ọmọ Juda rò, yóo jẹ àwọn ọmọ Israẹli níyà gẹ́gẹ́ bí ìwà wọn, yóo sì san ẹ̀san iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún wọn.

3. Jakọbu, baba ńlá wọn di arakunrin rẹ̀ ní gìgísẹ̀ mú ninu oyún, nígbà tí ó dàgbà tán, ó bá Ọlọrun wọ̀jàkadì.

4. Ó bá angẹli jà, ó ja àjàṣẹ́gun, ó sọkún, ó sì wá ojurere rẹ̀. Ó bá Ọlọrun pàdé ní Bẹtẹli, níbẹ̀ ni Ọlọrun sì ti bá a sọ̀rọ̀.

5. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, OLUWA ni orúkọ rẹ̀:

6. Nítorí náà, ẹ yipada nípa agbára Ọlọrun yín, ẹ di ìfẹ́ ati ìdájọ́ òdodo mú, kí ẹ sì dúró de Ọlọrun yín nígbà gbogbo.

Àwọn Ìdájọ́ Mìíràn

7. OLUWA ní, “Efuraimu jẹ́ oníṣòwò tí ó gbé òṣùnwọ̀n èké lọ́wọ́, ó sì fẹ́ràn láti máa ni eniyan lára.

8. Efuraimu ní, ‘Mo ní ọrọ̀, mo ti kó ọrọ̀ jọ fún ara mi, ṣugbọn gbogbo ọrọ̀ rẹ̀ kò lè mú ẹ̀bi rẹ̀ kúrò.’

9. Èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ láti ilẹ̀ Ijipti; n óo tún mú ọ pada gbé inú àgọ́, bí àwọn ọjọ́ àjọ ìyàsọ́tọ̀.

10. “Mo bá àwọn wolii sọ̀rọ̀; èmi ni mo fi ọpọlọpọ ìran hàn wọ́n, tí mo sì tipasẹ̀ wọn pa ọpọlọpọ òwe.

11. Ẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà wà ní Gileadi, dájúdájú yóo parun; bí wọ́n bá fi akọ mààlúù rúbọ ní Giligali, pẹpẹ wọn yóo dàbí òkúta tí a kójọ ní poro oko.”

12. Jakọbu sálọ sí ilẹ̀ Aramu, níbẹ̀ ni ó ti singbà, tí ó ṣiṣẹ́ darandaran, nítorí iyawo tí ó fẹ́.

13. Nípasẹ̀ wolii kan ni OLUWA ti mú Israẹli jáde kúrò ní Ijipti, nípasẹ̀ wolii kan ni a sì ti pa á mọ́.

14. Efuraimu ti mú èmi, OLUWA rẹ̀ bínú lọpọlọpọ, nítorí náà, n óo da ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ lé e lórí, òun tí ó gàn mí ni yóo di ẹni ẹ̀gàn.