orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Pe arakunrin rẹ ní “Eniyan mi” kí o sì pe arabinrin rẹ ní “Ẹni tí ó rí àánú gbà.”

Gomeri Alaiṣootọ–Israẹli Alaiṣootọ

2. Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀.

3. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo tú u sí ìhòòhò, n óo ṣe é bí ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i. N óo ṣe é bí aṣálẹ̀, àní, bí ilẹ̀ tí ó gbẹ, n óo sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ pa.

4. N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n.

5. Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.”

6. Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde.

7. Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.”

8. Kò gbà pé èmi ni mo fún òun ní oúnjẹ, tí mo fún un ní waini ati òróró, tí mo sì fún un ní ọpọlọpọ fadaka ati wúrà tí ó ń lò fún oriṣa Baali.

9. Nítorí náà n óo gba waini ati ọkà mi pada ní àkókò wọn, n óo sì gba aṣọ òtútù ati ẹ̀wù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun mi, tí kì bá fi bo ìhòòhò rẹ̀.

10. N óo tú u sí ìhòòhò lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.

11. N óo fi òpin sí ayọ̀ rẹ̀ ati ọjọ́ àsè rẹ̀, ọjọ́ oṣù tuntun rẹ̀, ọjọ́ ìsinmi rẹ̀, ati gbogbo àjọ̀dún tí ó ti yà sọ́tọ̀.

12. N óo run gbogbo igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, àwọn ohun tí ó ń pè ní owó ọ̀yà, tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ san fún un. N óo sọ ọgbà rẹ̀ di igbó, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo sì jẹ wọ́n ní àjẹrun.

13. N óo jẹ ẹ́ níyà fún àwọn ọjọ́ tí ó yà sọ́tọ̀, tí ó fi ń sun turari sí àwọn oriṣa Baali, tí ó kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀ sára, tí ó ń sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, tí ó sì gbàgbé mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

Ìfẹ́ OLUWA sí Àwọn Eniyan Rẹ̀

14. Nítorí náà, n óo tàn án lọ sinu aṣálẹ̀, n óo bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́.

15. N óo sì fún un ní àwọn ọgbà àjàrà rẹ̀ pada níbẹ̀, n óo sì sọ àfonífojì Akori di Ẹnu Ọ̀nà Ìrètí. Yóo kọrin fún mi bí ó tí ń ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀, nígbà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Ijipti dé.

16. OLUWA ní, nígbà tí ó bá yá, yóo máa pè mí ní ọkọ rẹ̀, kò ní pè mí ní Baali rẹ̀ mọ́.

17. Nítorí pé, n óo gba orúkọ Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀, kò sì ní dárúkọ rẹ̀ mọ́.

18. Nígbà náà ni n óo tìtorí tirẹ̀ bá àwọn ẹranko, àwọn ẹyẹ, ati àwọn nǹkan tí ń fi àyà fà lórí ilẹ̀ dá majẹmu, n óo sì mú ọfà, idà, ati ogun kúrò ní ilẹ̀ náà. N óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ní alaafia ati ní àìléwu.

19. Ìwọ Israẹli, n óo sọ ọ́ di iyawo mi títí lae;n óo sọ ọ́ di iyawo mi lódodo ati lótìítọ́,ninu ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ati àánú.

20. N óo sọ ọ́ di iyawo mi, lótìítọ́, o óo sì mọ̀ mí ní OLUWA.

21. OLUWA ní,“Ní ọjọ́ náà, n óo dáhùn adura ojú ọ̀run,ojú ọ̀run yó sì dáhùn adura ilẹ̀.

22. Ilẹ̀ yóo sì dáhùn adura ọkà, ati ti waini ati ti òróró.Àwọn náà óo sì dáhùn adura Jesireeli.

23. N óo fi ìdí àwọn eniyan mi múlẹ̀ ní ilẹ̀ náà,wọn yóo sì máa bí sí i.N óo ṣàánú ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kò sí àánú’,n óo sì sọ fún ẹni tí a tí ń pè ní ‘Kì í ṣe eniyan mi’ pé eniyan mi ni;òun náà yóo sì dá mi lóhùn pé,‘Ìwọ ni Ọlọrun mi.’ ”