Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 38:5-11 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ó da òrùka mẹrin, ó jó ọ̀kọ̀ọ̀kan mọ́ igun kọ̀ọ̀kan ayanran idẹ náà, àwọn òrùka wọnyi ni wọ́n máa ń ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé pẹpẹ náà.

6. Ó fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì yọ́ idẹ bò wọ́n.

7. Ó ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà láti máa fi gbé e; pákó ni ó fi ṣe àwọn ọ̀pá náà, wọ́n sì ní ihò ninu.

8. Ó mu dígí onídẹ, tí àwọn obinrin tí ń ṣiṣẹ́ ìsìn lẹ́nu ọ̀nà àgọ́ ń lò, ó fi ṣe agbada idẹ kan, ati ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀.

9. Ó ṣe àgbàlá kan, aṣọ funfun, onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni ó fi ṣe aṣọ títa ìhà gúsù àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ.

10. Ogún ni àwọn òpó aṣọ títa, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn náà sì jẹ́ ogún. Idẹ ni ó fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni ó fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

11. Gígùn apá àríwá àgọ́ náà jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ pẹlu, ogún ni àwọn òpó rẹ̀, àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn sì jẹ́ ogún pẹlu. Idẹ ni wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ wọn, ṣugbọn fadaka ni wọ́n fi ṣe ìkọ́ ati àwọn ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ wọn.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 38