Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 7:9-23 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí náà, ẹ máa ranti pé OLUWA Ọlọrun yín ni Ọlọrun, Ọlọrun olótìítọ́ tíí pa majẹmu mọ́, tíí sì ń fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn sí àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́, títí dé ẹgbẹrun ìran,

10. a sì máa san ẹ̀san lojukooju fún àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀. Yóo pa wọ́n run, kò ní dáwọ́ dúró láti má gba ẹ̀san lára gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ̀, yóo san ẹ̀san fún wọn ní ojúkoojú.

11. Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra kí ẹ sì máa pa òfin rẹ̀ mọ́, kí ẹ sì tẹ̀lé ìlànà ati ìdájọ́ rẹ̀ tí mo fun yín lónìí.

12. “Bi ẹ bá fetí sí òfin wọnyi, tí ẹ sì pa wọ́n mọ́, OLUWA Ọlọrun yín yóo mú majẹmu tí ó bá àwọn baba yín dá ṣẹ lórí yín, yóo sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ̀ hàn yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fún wọn.

13. Yóo fẹ́ràn yín, yóo bukun yín, yóo sọ yín di pupọ, yóo bukun àwọn ọmọ yín, ati èso ilẹ̀ yín, ati ọkà yín, ọtí waini yín, ati òróró yín; yóo bukun àwọn mààlúù yín, yóo sì mú kí àwọn ẹran ọ̀sìn yín kéékèèké pọ̀ sí i, ní ilẹ̀ tí ó ti búra láti fún àwọn baba yín.

14. OLUWA yóo bukun yín ju gbogbo àwọn eniyan yòókù lọ; kò ní sí ọkunrin kan tabi obinrin kan tí yóo yàgàn láàrin yín, tabi láàrin àwọn ẹran ọ̀sìn yín.

15. OLUWA yóo mú gbogbo àrùn kúrò lọ́dọ̀ yín, kò sì ní fi ẹyọ kan ninu gbogbo àwọn àrùn burúkú ilẹ̀ Ijipti, tí ẹ mọ̀, ba yín jà. Ṣugbọn yóo dà wọ́n bo àwọn tí wọ́n kórìíra yín.

16. Píparun ni ẹ óo pa gbogbo àwọn eniyan tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi lé yín lọ́wọ́ run, ẹ kò gbọdọ̀ ṣàánú wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ bọ àwọn oriṣa wọn, nítorí ohun ìkọsẹ̀ ni wọn yóo jẹ́ fun yín.

17. “Bí ẹ bá rò ní ọkàn yín pé àwọn eniyan wọnyi pọ̀ jù yín lọ, ati pé báwo ni ẹ ṣe lè lé wọn jáde,

18. ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Farao ati gbogbo ilẹ̀ Ijipti. Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ bẹ̀rù wọn.

19. Ẹ ranti àwọn àrùn burúkú tí ẹ fi ojú ara yín rí, àwọn àmì ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ agbára tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe kí ó tó kó yín jáde. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni OLUWA Ọlọrun yín yóo ṣe sí gbogbo àwọn eniyan tí ẹ̀ ń bẹ̀rù.

20. OLUWA Ọlọrun yín yóo rán agbọ́n sí wọn títí tí gbogbo àwọn tí wọ́n bá farapamọ́ fun yín yóo fi parun.

21. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹ̀rù wọn bà yín, nítorí pé Ọlọrun tí ó tóbi, tí ó sì ní ẹ̀rù ni OLUWA Ọlọrun yín tí ó wà láàrin yín.

22. Díẹ̀díẹ̀ ni Ọlọrun yóo lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí lọ. Kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni ẹ óo pa gbogbo wọn run, kí àwọn ẹranko burúkú má baà pọ̀ ní ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì ju agbára yín lọ.

23. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun yín yóo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, yóo sì mú kí ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ sílẹ̀ ní ààrin wọn títí tí wọn yóo fi parun.

Ka pipe ipin Diutaronomi 7