Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 18:13-26 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ní ọdún kẹrinla tí Hesekaya jọba ní Juda, ni Senakeribu, ọba Asiria, gbógun ti àwọn ìlú olódi Juda, ó sì ṣẹgun wọn.

14. Hesekaya ranṣẹ sí Senakeribu, ọba Asiria, tí ó wà ní Lakiṣi nígbà náà, ó ní: “Mo ti ṣẹ̀, jọ̀wọ́ dá ọwọ́ ogun rẹ dúró; n óo sì san ohunkohun tí o bá bèèrè.” Ọba náà sì bèèrè fún ọọdunrun ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ọgbọ̀n ìwọ̀n talẹnti wúrà lọ́wọ́ Hesekaya ọba Juda.

15. Hesekaya bá kó gbogbo fadaka tí ó wà ninu ilé OLUWA ati ti inú ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ranṣẹ sí i.

16. Ó sì ṣí wúrà tí ó wà lára ìlẹ̀kùn ilé OLUWA ati wúrà tí òun tìkararẹ̀ fi bo àwọn òpó ìlẹ̀kùn, ó kó wọn ranṣẹ sí Senakeribu.

17. Ọba Asiria rán àwọn ọ̀gágun rẹ̀: Tatani, Rabusarisi ati Rabuṣake pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun láti Lakiṣi láti gbógun ti Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu wọ́n dúró sí ibi ọ̀nà tí àwọn tí wọn ń hun aṣọ tí ń ṣiṣẹ́, lẹ́bàá kòtò omi tí ń ṣàn wá láti adágún omi tí ó wà ninu ìlú lápá òkè.

18. Nígbà tí wọ́n ké sí Hesekaya ọba, Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó ń ṣe àkóso ààfin, ati Ṣebina akọ̀wé ọba, ati Joa ọmọ Asafu, tí ń ṣe àkóso ìwé ìrántí ni wọ́n jáde sí wọn.

19. Rabuṣake ní, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé, ọba ńlá, ọba ilẹ̀ Asiria ní kí ni ó gbẹ́kẹ̀lé?

20. Ṣé ó rò pé ọ̀rọ̀ lásán lè dípò ọgbọ́n ati agbára ogun ni? Ó ní, ta ni Hesekaya gbẹ́kẹ̀lé tí ó fi ń dìtẹ̀ mọ́ òun?

21. Ṣé Ijipti ni ó gbójú lé pé yóo ran òun lọ́wọ́? Ó ní ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí ẹni tí ó ń fi igi tí kò ní agbára ṣe ọ̀pá ìtilẹ̀. Tí igi náà bá dá, yóo gún un lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ijipti rí sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.

22. “Ṣugbọn tí ẹ bá sọ fún mi pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé OLUWA Ọlọrun yín, ṣebí àwọn ibi ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ Ọlọrun náà ni Hesekaya ti bàjẹ́, tí ó sì sọ fún àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu pé, ‘Níwájú pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu nìkan ni kí ẹ ti máa sìn.’

23. Nisinsinyii, ẹ wá ṣe àdéhùn pẹlu ọba Asiria, oluwa mi. N óo fun yín ní ẹgbaa (2,000) ẹṣin bí ẹ bá lè rí ẹgbaa (2,000) eniyan tí yóo gùn wọ́n.

24. Ẹ kò lè ṣẹgun ẹni tí ó kéré jùlọ ninu àwọn ọ̀gágun ọba Asiria, sibẹ o rò pé àwọn kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin ọba Ijipti yóo ràn ọ́ lọ́wọ́.

25. Ṣé o rò pé lásán ni mo wá láti pa ilẹ̀ yìí run, láìsí ìrànlọ́wọ́ OLUWA? OLUWA fúnra rẹ̀ ni ó sọ fún mi pé kí n wá pa ilẹ̀ yìí run.”

26. Nígbà náà ni Eliakimu, ọmọ Hilikaya ati Ṣebina ati Joa sọ fún Rabuṣake pé, “Jọ̀wọ́, bá àwa iranṣẹ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè Aramaiki nítorí pé a gbọ́. Má sọ èdè Heberu mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n wà lórí odi ń gbọ́ ohun tí ò ń sọ.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 18