Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 15:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Jeroboamu jọba ní Israẹli ni Asaraya ọmọ Amasaya, jọba ní Juda.

2. Ẹni ọdún mẹrindinlogun ni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún mejilelaadọta. Jekolaya ará Jerusalẹmu ni ìyá rẹ̀.

3. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú OLUWA nítorí pé ó tẹ̀lé ọ̀nà Amasaya, baba rẹ̀.

4. Ṣugbọn kò pa àwọn pẹpẹ oriṣa run, àwọn eniyan ṣì ń rúbọ; wọ́n sì ń sun turari níbẹ̀.

5. OLUWA sọ Asaraya ọba di adẹ́tẹ̀, ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀, ó ń dá gbé. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì ń ṣàkóso ìjọba nípò rẹ̀.

6. Gbogbo nǹkan yòókù tí Asaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda.

7. Ó kú, wọ́n sì sin ín sinu ibojì àwọn ọba ní ìlú Dafidi, Jotamu, ọmọ rẹ̀, sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

8. Ní ọdún kejidinlogoji tí Asaraya jọba ní Juda ni Sakaraya ọmọ Jeroboamu jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó sì wà lórí oyè fún oṣù mẹfa.

9. Ó ṣe ohun burúkú níwájú OLUWA gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe. Ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu; ọmọ Nebati, tí ó mú Israẹli dẹ́ṣẹ̀.

10. Ṣalumu ọmọ Jabeṣi dìtẹ̀ mọ́ ọn, ó pa á ní Ibileamu, ó sì jọba dípò rẹ̀.

11. Gbogbo nǹkan yòókù tí Sakaraya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

12. OLUWA ṣèlérí fún Jehu pé, “Àwọn ọmọ rẹ títí dé ìran kẹrin yóo jọba ní Israẹli.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.

13. Ní ọdún kọkandinlogoji tí Asaraya ti jọba ní Juda ni Ṣalumu, ọmọ Jabeṣi, jọba lórí Israẹli, ní Samaria, ó wà lórí oyè fún oṣù kan.

14. Menahemu ọmọ Gadi lọ sí Samaria láti Tirisa, ó pa Ṣalumu ọba, ó sì jọba dípò rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 15