Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 11:21-39 BIBELI MIMỌ (BM)

21. OLUWA Ọlọrun Israẹli bà fi Sihoni ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, Israẹli ṣẹgun wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé agbègbè náà.

22. Wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori láti Anoni títí dé odò Jaboku ati láti aṣálẹ̀ títí dé odò Jọdani.

23. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ó gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Amori fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣé ìwọ wá fẹ́ gbà á ni?

24. Ṣé ohun tí Kemoṣi, oriṣa rẹ fún ọ, kò tó ọ ni? Gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun wa ti gbà fún wa ni a óo fọwọ́ mú.

25. Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí?

26. Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà?

27. Nítorí náà, n kò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ ni o ṣẹ̀ mí, nítorí pé o gbógun tì mí. Kí OLUWA onídàájọ́ dájọ́ lónìí láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati Amoni.”

28. Ṣugbọn ọba àwọn ará Amoni kò tilẹ̀ fetí sí iṣẹ́ tí Jẹfuta rán sí i rárá.

29. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé Jẹfuta, ó bá kọjá láàrin Gileadi ati Manase, ó lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Gileadi, láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

30. Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni,

31. nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.”

32. Jẹfuta bá rékọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Amoni láti bá wọn jagun, OLUWA sì fún un ní ìṣẹ́gun.

33. Ó bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n láti Aroeri títí dé agbègbè Miniti tí ó fi wọ Abeli Keramimu. Àwọn ìlú tí ó run jẹ́ ogún. Àwọn ọmọ Israẹli sì ṣẹgun àwọn ará Amoni.

34. Jẹfuta bá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ nì Misipa, bí ó ti ń wọ̀lú bọ̀, ọmọ rẹ̀ obinrin wá pàdé rẹ̀ pẹlu ìlù ati ijó, ọmọbinrin yìí sì ni ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí.

35. Bí ó ti rí i, ó fa aṣọ rẹ̀ ya ó ní, “Ha! Ọmọ mi, ìwọ ni o kó mi sinu ìbànújẹ́ yìí? Ó ṣe wá jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tìrẹ ni yóo kó ìbànújẹ́ bá mi? Nítorí pé mo ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú OLUWA n kò sì gbọdọ̀ má mú un ṣẹ.”

36. Ọmọbinrin náà dá baba rẹ̀ lóhùn pé, “Baba mi, bí o bá ti jẹ́jẹ̀ẹ́ kan níwájú OLUWA, ṣe sí mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀jẹ́ rẹ níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbẹ̀san lára àwọn ará Amoni, tí í ṣe ọ̀tá rẹ.”

37. Ó bá bẹ baba rẹ̀, ó ní, “Kinní kan ni mo fẹ́ kí o ṣe fún mi, fi mí sílẹ̀ fún oṣù meji, kí èmi ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi lọ sí orí òkè kí á máa káàkiri, kí á sì máa sọkún, nítorí pé mo níláti kú láì mọ ọkunrin.”

38. Baba rẹ̀ bá ní kí ó máa lọ fún oṣù meji. Òun ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá lọ sí orí òkè, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọkún, nítorí pé ó níláti kú, láì mọ ọkunrin.

39. Lẹ́yìn oṣù meji, ó pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀, baba rẹ̀ sì ṣe bí ó ti jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun yóo ṣe, ọmọbinrin náà kò mọ ọkunrin rí rárá.Ó sì di àṣà ní ilẹ̀ Israẹli,

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 11