Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Adájọ́ 11:17-32 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti rán oníṣẹ́ sí ọba Edomu, wọ́n ní, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ yín kọjá.’ Ṣugbọn ọba Edomu kò gbà wọ́n láàyè rárá, bákan náà, wọ́n ranṣẹ sí ọba Moabu, òun náà kò fún wọn láàyè, àwọn ọmọ Israẹli bá jókòó sí Kadeṣi.

18. Wọ́n bá gba aṣálẹ̀, wọ́n sì yípo lọ sí òdìkejì ilẹ̀ àwọn ará Edomu ati ti àwọn ará Moabu, títí tí wọ́n fi dé apá ìlà oòrùn ilẹ̀ àwọn ará Moabu. Wọ́n pàgọ́ wọn sí òdìkejì ilẹ̀ Anoni. Ṣugbọn wọn kò wọ inú ilẹ̀ àwọn ará Moabu, nítorí pé, ààlà ilẹ̀ Moabu ni Anoni wà.

19. Israẹli bá tún rán oníṣẹ́ sí Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ó wà ní ìlú Heṣiboni, wọ́n ní, ‘Jọ̀wọ́ jẹ́ kí á gba ilẹ̀ rẹ kọjá lọ sí agbègbè ilẹ̀ tiwa.’

20. Ṣugbọn Sihoni kò ní igbẹkẹle ninu àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn kọjá láàrin ilẹ̀ rẹ̀. Ó bá kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, wọ́n pàgọ́ sí Jahasi, wọ́n sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

21. OLUWA Ọlọrun Israẹli bà fi Sihoni ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ lé Israẹli lọ́wọ́, Israẹli ṣẹgun wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọ́n ń gbé agbègbè náà.

22. Wọ́n gba gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amori láti Anoni títí dé odò Jaboku ati láti aṣálẹ̀ títí dé odò Jọdani.

23. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli ni ó gba ilẹ̀ náà lọ́wọ́ àwọn ará Amori fún àwọn ọmọ Israẹli. Ṣé ìwọ wá fẹ́ gbà á ni?

24. Ṣé ohun tí Kemoṣi, oriṣa rẹ fún ọ, kò tó ọ ni? Gbogbo ohun tí OLUWA Ọlọrun wa ti gbà fún wa ni a óo fọwọ́ mú.

25. Ṣé ìwọ sàn ju Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu lọ ni? Ǹjẹ́ Balaki bá àwọn ọmọ Israẹli ṣe ìjàngbọ̀n kan tabi kí ó bá wọn jagun rí?

26. Fún nǹkan bí ọọdunrun (300) ọdún tí Israẹli fi ń gbé Heṣiboni ati Aroeri, ati àwọn ìletò tí ó wà ní agbègbè wọn, ati àwọn ìlú ńláńlá tí ó wà ní etí odò Anoni, kí ló dé tí o kò fi gba ilẹ̀ rẹ láàrin àkókò náà?

27. Nítorí náà, n kò ṣẹ̀ ọ́ rárá, ìwọ ni o ṣẹ̀ mí, nítorí pé o gbógun tì mí. Kí OLUWA onídàájọ́ dájọ́ lónìí láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati Amoni.”

28. Ṣugbọn ọba àwọn ará Amoni kò tilẹ̀ fetí sí iṣẹ́ tí Jẹfuta rán sí i rárá.

29. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé Jẹfuta, ó bá kọjá láàrin Gileadi ati Manase, ó lọ sí Misipa ní ilẹ̀ Gileadi, láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

30. Jẹfuta bá jẹ́jẹ̀ẹ́ kan sí OLUWA, ó ní, “OLUWA, bí o bá ràn mí lọ́wọ́ tí mo bá ṣẹgun àwọn ara Amoni,

31. nígbà tí mo bá ń pada bọ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ṣẹgun wọn tán, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ jáde láti wá pàdé mi láti inú ilé mi, yóo jẹ́ ti ìwọ OLUWA, n óo sì fi rú ẹbọ sísun sí ọ.”

32. Jẹfuta bá rékọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Amoni láti bá wọn jagun, OLUWA sì fún un ní ìṣẹ́gun.

Ka pipe ipin Àwọn Adájọ́ 11