Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 65:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo ṣetán láti mú kí àwọn tí kò bèèrè mi máa wá mi,ati láti fi ara mi han àwọn tí kò wá mi.Mo sọ fún orílẹ̀-èdè tí kì í gbadura ní orúkọ mi pé,“Èmi nìyí, èmi nìyí.”

2. Láti òwúrọ̀ di alẹ́, mo na ọwọ́ mi sí àwọn ọlọ̀tẹ̀ eniyan;àwọn tí wọn ń rìn ní ọ̀nà tí kò dára,tí wọn ń tẹ̀lé èrò ọkàn wọn,

3. tí wọn ń ṣe ohun tí yóo mú mi bínú,níṣojú mi, nígbà gbogbo.Wọ́n ń rúbọ ninu oríṣìíríṣìí ọgbà,wọ́n ń sun turari lórí bíríkì.

4. Àwọn tí wọn ń jókòó sí itẹ́ òkú,tí wọn ń dúró níbi ìkọ̀kọ̀ lóru;àwọn tí wọn ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀,tí ìṣaasùn ọbẹ̀ wọn sì kún fún ẹran aláìmọ́.

5. Wọn á máa ké pé, “Yàgò lọ́nà. Má fara kàn mí,nítorí mo jẹ́ ẹni mímọ́ jù ọ́ lọ.”Ṣugbọn bí èéfín ni irú wọn rí ní ihò imú mi,bí iná tí ó ń jó lojoojumọ.

6. Wò ó! A ti kọ ọ́ sílẹ̀ níwájú mi pé,“N kò ní dákẹ́, ṣugbọn n óo gbẹ̀san.

7. N óo gbẹ̀san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lára wọn,ati ti àwọn baba wọn.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí pé wọ́n ń sun turari lórí àwọn òkè ńlá,wọ́n sì ń fi mí ṣẹ̀sín lórí àwọn òkè kéékèèké.N óo san ẹ̀san iṣẹ́ wọn àtẹ̀yìnwá fún wọn.

8. “Bí eniyan tíí wòye pé ọtí wà lára ìdì èso àjàrà,tí wọn sìí sọ pé, ‘Ẹ má bà á jẹ́,nítorí ohun rere wà ninu rẹ̀,’bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe nítorí iranṣẹ mi,n kò ní pa gbogbo wọn run.

9. N óo mú kí arọmọdọmọ jáde lára Jakọbu,àwọn tí yóo jogún òkè ńlá mi yóo sì jáde láti ara Juda.Àwọn tí mo ti yàn ni yóo jogún rẹ̀,àwọn iranṣẹ mi ni yóo sì máa gbé ibẹ̀.

10. Ilé Ṣaroni yóo di ibùjẹ ẹran,àfonífojì Akori yóo sì di ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn yóo máa dùbúlẹ̀ sí,fún àwọn eniyan mi, tí wọ́n wá mi.

11. “Ṣugbọn níti ẹ̀yin tí ẹ kọ mí sílẹ̀,tí ẹ gbàgbé Òkè Mímọ́ mi,tí ẹ tẹ́ tabili sílẹ̀ fún Gadi, oriṣa Oríire,tí ẹ̀ ń po àdàlú ọtí fún Mẹni, oriṣa Àyànmọ́.

12. N óo fi yín fún ogun pa,gbogbo yín ni ẹ óo sì bọ́ sọ́wọ́ àwọn apànìyàn;nítorí pé nígbà tí mo pè yín, ẹ kò dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹ kò gbọ́,ẹ ṣe nǹkan tí ó burú lójú mi;ẹ yan ohun tí inú mi kò dùn sí.

13. Wò ó, àwọn iranṣẹ mi yóo máa rí oúnjẹ jẹ,ṣugbọn ebi yóo máa pa yín;àwọn iranṣẹ mi yóo mu waini,ṣugbọn òùngbẹ yóo máa gbẹ yín.Àwọn iranṣẹ mi yóo máa yọ̀,ṣugbọn ìtìjú yóo máa ba yín.

14. Àwọn iranṣẹ mi yóo máa kọrin nítorí inú wọn dùn,ṣugbọn ẹ̀yin óo máa kígbe oró àtọkànwá;ẹ óo sì máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, nítorí àròkàn.

Ka pipe ipin Aisaya 65