Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Aisaya 60:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ta ni àwọn wọnyi tí ń fò lọ bí ìkùukùu?Bí ìgbà tí àwọn àdàbà bá ń fò lọ sí ibi ìtẹ́ wọn?

9. Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí,ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwajuwọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè,wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn;nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ,ati Ẹni Mímọ́ Israẹli,nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo.

10. OLUWA ní, “Àwọn àjèjì ni yóo máa tún odi rẹ mọ,àwọn ọba wọn yóo sì máa ṣe iranṣẹ fún ọ;nítorí pé inú ló bí mi ni mo fi nà ọ́.Ṣugbọn nítorí ojurere mi ni mo fi ṣàánú fún ọ.

11. Ṣíṣí ni ìlẹ̀kùn rẹ yóo máa wà nígbà gbogbo,a kò ní tì wọ́n tọ̀sán-tòru;kí àwọn eniyan lè máa kó ọrọ̀ orílẹ̀-èdè wá fún ọ,pẹlu àwọn ọba wọn tí wọn yóo máa tì siwaju.

12. Orílẹ̀-èdè tabi ilẹ̀ ọba tí kò bá sìn ọ́ yóo parun,wọn óo di àwópalẹ̀ patapata.

13. “Ògo Lẹbanoni yóo wá sí ọ̀dọ̀ rẹ:igi sipirẹsi, igi firi, ati igi pine;láti bukun ẹwà ilé mímọ́ mi,n óo sì ṣe ibi ìtìsẹ̀ mi lógo.

14. Àwọn ọmọ àwọn tí ń ni ọ́ lára yóo wá,wọn óo tẹríba fún ọ;gbogbo àwọn tí ń kẹ́gàn rẹ,yóo wá tẹríba lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ;wọn óo pè ọ́ ní ìlú OLÚWA,Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

15. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kọ̀ ọ́,wọ́n sì kórìíra rẹ,tí kò sí ẹni tí ń gba ààrin rẹ̀ kọjá mọ́,n óo sọ ọ́ di àmúyangàn títí lae;àní, ohun ayọ̀ láti ìrandíran.

16. O óo mu wàrà àwọn orílẹ̀-èdè,o óo mu wàrà àwọn ọba.O óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA, ni olùgbàlà rẹ,ati Olùràpadà rẹ, Ẹni Ńlá Jakọbu.

17. “Dípò bàbà, wúrà ni n óo mú wá.Dípò irin, fadaka ni n óo mú wá.Dípò igi, bàbà ni n óo mú wá.Dípò òkúta, irin ni n óo mú wá.N óo mú kí àwọn alabojuto yín wà ní alaafia,àwọn akóniṣiṣẹ́ yín yóo sì máa ṣe òdodo.

Ka pipe ipin Aisaya 60