Nítorí àwọn erékùṣù yóo dúró dè mí,ọkọ̀ ojú omi Taṣiṣi ni yóo ṣiwajuwọn óo kó àwọn ọmọkunrin rẹ wá láti ilẹ̀ òkèèrè,wọn óo kó wúrà ati fadaka wá pẹlu wọn;nítorí orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ,ati Ẹni Mímọ́ Israẹli,nítorí ó ti ṣe ọ́ lógo.