Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Mátíù 21:3-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Bí ẹnikẹ́ni bá sì béèrè ìdí tí ẹ fi ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ sáà wí pé, Olúwa ní wọn-ọ́n lò, òun yóò sì rán wọn lọ.”

4. Èyí ṣẹlẹ̀ láti mú àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì ṣẹ pé:

5. “Ẹ sọ fún ọmọbìnrin Síónì pé,‘Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,ní ìrẹ̀lẹ̀, ó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,àti lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.’ ”

6. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà sí lọ, wọ́n ṣe bí Jésù ti sọ fún wọn

7. Wọ́n sì mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà pẹ̀lú ọmọ rẹ̀, wọ́n tẹ́ aṣọ lé e, Jésù si jókòó lórí rẹ̀.

8. Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tẹ́ aṣọ wọn sí ojú ọ̀nà níwájú rẹ̀, ẹlòmíràn sẹ́ ẹ̀ka igi wẹ́wẹ́ wọ́n sì tẹ́ wọn sí ojú ọ̀nà.

9. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ níwájú rẹ̀ àti lẹ́yìn rẹ̀ pẹ̀lú ń kígbe pé,“Hòsánà fún ọmọ Dáfídì!”“Olùbùkún ni fún ẹni tí ó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa!”“Hòsánà ní ibi gíga jùlọ!”

10. Bí Jésù sì ti ń wọ Jerúsálémù, gbogbo ìlú mì tìtì, àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bi ara wọn pé, “Ta nì yìí?”

11. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì dáhùn pé, “Èyí ni Jésù, wòlíì náà láti Násárẹ́tì ti Gálílì.”

12. Jésù sì wọ inú tẹ́ḿpì Ọlọ́run. Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàsípààrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlẹ́.

13. Ó wí fún wọn pé, “A sáà ti kọ ọ́ pé, ‘Ilé àdúrà ni a ó máa pe ilé mi’, ṣùgbọn ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ibùdó àwọn ọlọ́ṣà.”

14. A sì mú àwọn afọ́jú àti àwọn arọ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní tẹ̀ḿpìlì, ó sì mú wọ́n láradá

15. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin rí àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá wọ̀nyí, ti wọ́n sì tún ń gbọ́ tí àwọn ọmọdé ń kigbé nínú tẹ́ḿpìlì pé, “Hòsánà fún ọmọ Dáfídì,” inú bí wọn.

16. Wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ ìwọ gbọ́ nǹkan tí àwọn ọmọdé wọ̀nyí ń sọ?”Jésù sí dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni,”“Àbí ẹ̀yin kò kà á pé ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ-ọmú,ni a ó ti máa yìn mí’?”

17. Ó sì fi wọ́n sílẹ̀, ó lọ sí Bẹ́tánì. Níbẹ̀ ni ó dúró ní òru náà.

18. Ní òwúrọ̀ bí ó ṣe ń padà sí ìlú, ebi ń pa á.

19. Ó sì ṣàkíyèsí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan lẹ́bàá ojú ọ̀nà, ó sì lọ wò ó bóyá àwọn èso wà lórí rẹ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹyọ kan, ewé nìkan ni ó wà lórí rẹ̀. Nígbà náà ni ó sì wí fún igi náà pé, “Kí èso má tún so lórí rẹ mọ́.” Lójú kan náà igi ọ̀pọ̀tọ́ náà sì gbẹ.

20. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rí èyí, ẹnú yà wọn, wọ́n béèrè pé, “Báwo ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà ṣe gbẹ kíákíà?”

Ka pipe ipin Mátíù 21