Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 9:21-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Jésù béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?”Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”

22. Nígbàkúùgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná ati sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.

23. “Jéṣù sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó seé ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”

24. Lójúkan-náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”

25. Nígbà tí Jésù rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”

26. Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàn tàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Héè, ọmọ náà ti kú.”

27. Ṣùgbọ́n Jésù fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó díde dúró.

28. Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè ní kọ́kọ́ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?”

29. Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò se nípa àdúrà.”

30. Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Gálílì kọjá. Níbẹ̀ ni Jésù ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i.

31. Nítorí o kọ̀ awọn Ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, o si wí fun wọn pe, “A o fi Ọmọ ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ijọ́ kẹta.”

32. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.

33. Wọ́n dé sí Kapanámù. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”

34. Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé ta ni ó ga jùlọ láàrin àwọn?

35. Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”

36. Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

37. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gba ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”

38. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa.”

Ka pipe ipin Máàkù 9