Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 8:22-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisáídà, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.

23. Jésù fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yin ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsìn yìí?”

24. Ọkùnrin náà wò àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”

25. Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.

26. Jésù sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹni ní ìlú.”

27. Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́?”

28. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé.”

29. Nígbà náà, Jésù bèèrè, “Ta ni ẹ̀yin gan-an rò pé mo jẹ́?”Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà.”

30. Ṣùgbọ́n Jésù kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.

31. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le má sàì jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde.

32. Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.

33. Jésù yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Pétérù pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Sátánì, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”

34. Nígbà náà ni Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó ṣe ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn.

35. Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìn rere, òun náà ni yóò gbà á là.

36. Nítorí èrè kí ni ó jẹ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù.?

37. Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàsípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?

38. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panságà àti ẹlẹ́sẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ-Ènìyàn yóò tijú rẹ nígbà tí o bá padà dé nínú ògo Baba rẹ, pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì mímọ́.”

Ka pipe ipin Máàkù 8