Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 2:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn.

3. Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé.

4. Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jésù, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jésù wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ẹní rẹ̀ níwájú Jésù.

5. Nígbà tí Jésù sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

6. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú àwọn olùkọ́ òfin tó jókòó níbẹ̀ sọ fún ara wọn pé,

7. “È é ṣe ti ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? O ń sọ̀rọ̀ òdì. Ta ni ó lè darí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bí ko ṣe Ọlọ́run nìkan?”

8. Lojú kan náà bí Jésù tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “È é ṣe tí ẹ̀yìn fí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

9. Èwo ni ó rọrùn jù láti wí fún arọ náà pé: ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde sì gbé àkéte rẹ, ki o si máa rin?’

10. Ṣùgbọ́n ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Ènìyàn ní agbára ní ayé làti dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ji ní.” Ó wí fún ọkùnrin arọ náà pé,

11. “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ẹní rẹ kí ó sì máa lọ ilé rẹ.”

12. Lójúkan-náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé ẹní rẹ̀. Ó sì jáde lọ lojú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”

13. Nígbà náà, Jésù tún jáde lọ sí etí òkun. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn.

14. Bí ó ti ń rin etí òkun lọ sókè, ó rí Léfì ọmọ Álíféù tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jésù sì wí fún un pé, “Tẹ̀ lé mi,” Léfì dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.

Ka pipe ipin Máàkù 2