Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Máàkù 11:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ sí abúlé tó wà lọ́hùn-ún nì. Nígbà tí ẹ bá sì wọlé, ẹ̀yin yóò rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí a so mọ́lẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ì tí i gùn rí. Ẹ tú u, kí ẹ sì mú wá síhìn-ín.

3. Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń se èyí?’ Ẹ sọ fún un pé, ‘Olúwa ní í fi ṣe, yóò sì dá a padà síbí láìpẹ́.’ ”

4. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà lọ bí ó ti rán wọn. Wọ́n rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó dúró ní ìta gbangba tí a so mọ́lẹ̀.

5. Bí wọ́n ti ń tú u, díẹ̀ nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀ bi wọ́n léèrè pé, “Kí ni ẹ̀ ń ṣe, È ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́?”

6. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì wọ̀nyí sọ ohun tí Jésù ní kí wọ́n sọ. Nítorí náà àwọn ènìyàn náà yọ̀ǹda fún wọn láti mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà lọ.

7. Wọ́n mú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà tọ Jésù wá. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì bọ́ ẹ̀wù wọn, wọ́n sì tẹ́ ẹ sí ẹ̀yìn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà fún Jésù láti jókòó lórí rẹ̀.

8. Nígbà náà, púpọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ àṣọ wọn sójú-ọ̀nà níwájú u rẹ̀. Àwọn mìíràn ju ewéko ìgbẹ́ sílẹ̀.

9. Jésù wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn níwájú, lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,“Hòsánà!”“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”

10. “Olubùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dáfídì, baba wa!”“Hòsánà lókè ọ̀run!”

11. Jésù wọ Jerúsálémù ó sì lọ sí inú tẹ́ḿpílì. Ó wo ohun gbogbo yíká fínnífínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti sú. Ó padà lọ sí Bẹ́tanì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.

12. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọ́n ti kúrò ní Bẹ́tanì, ebi ń pa Jésù.

Ka pipe ipin Máàkù 11