Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 21:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Símónì ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi bí?”Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

17. Ó wí fún un nígbà kẹ́ta pé, “Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ràn mi bí?”Inú Pétérù sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹ́ta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”Jésù wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

18. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ ó na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.

19. (Ó wí èyí, ó fi ń ṣàpẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo.) Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

20. Pétérù sì yípadà, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn náà, ẹni tí Jésù fẹ́ràn, ń bọ̀ lẹ́yìn; ẹni tí ó fararọ̀ súnmọ́ àyà rẹ̀ nígbà oúnjẹ alẹ́ tí ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ta ni ẹ̀ni tí ó fi ọ́ hàn?”

21. Nígbà tí Pétérù rí i, ó wí fún Jésù pé, “Olúwa, Eléyìí ha ńkọ́?”

22. Jésù wí fún un pé, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ? Ìwọ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

23. Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrin àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jésù kò wí fún un pé, Òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kínni èyí jẹ́ sí ọ?”

24. Èyí ni ọmọ-ẹ̀yìn náà, tí ó jẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí àwa sì mọ̀ pé, òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.

25. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun mìíràn pẹ̀lú ni Jésù ṣe, èyí tí bí a bá kọ̀wé wọn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé gbogbo ayé pàápàá kò lè gba ìwé náà tí a bá kọ ọ́. Àmín

Ka pipe ipin Jòhánù 21