Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jòhánù 15:16-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èṣo yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá bèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín.

17. Nǹkan wọ̀nyí ni mo paláṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.

18. “Bí ayé bá kóríra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kóríra mi ṣáájú yín.

19. Ìbáṣepé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ àwọn tirẹ̀; ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín.

20. Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa ti yín mọ́ pẹ̀lú.

21. Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ó ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi.

22. Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

23. Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú.

24. Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàárin wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra àti èmi àti Baba mi.

25. Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

Ka pipe ipin Jòhánù 15