orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Olórí Àlùfáà Ti Májẹ̀mú Tuntun

1. Nísinsin yìí, kókó ohun tí à ń sọ nìyí: Àwá ní irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀, tí ó jokòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ ọla ńlá nínú àwọn ọ̀run:

2. Ìránṣẹ́ ibi mímọ́, àti ti àgọ́ tóòtọ́, tí Olúwa pa, kì í ṣe ènìyàn.

3. Nítorí a fi olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan jẹ láti máa mú ẹ̀bùn wá láti máa rúbọ: Nítorí náà ó ṣe pàtàkì fún eléyìí náà láti ní nǹkan tí ó máa fi sílẹ̀.

4. Tí ó bá jẹ́ pé ó wà ní ayé ni, òun kì bá ti jẹ́ àlùfáà, nítorí pé àwọn ọkùnrin tí ó ń fi ẹ̀bùn sílẹ̀ ti wà bí òfin ṣe là á sílẹ̀.

5. Àwọn ẹni tí ń sìn nínú pẹpẹ kan tí ó jẹ́ ẹ̀dá àti òjìji ohun tí ń lọ́run. Ìdí abájọ nìyí tí a fi kìlọ̀ fún Mósè nígbà tí ó kọ́ àgọ́: Nítorí ó wí pé, “Kíyèsí kí o ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí a fihàn ọ lórí òkè.”

6. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí o ti gba iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó ni ọlá jù, níwọ̀n bí o ti jẹ pé alárinà májẹ̀mú tí o dára jù ní i ṣe, èyí tí a fi ṣe òfin lórí ìlérí tí o sàn jù bẹ́ẹ̀ lọ.

7. Nítorí ìbá ṣe pé májẹ̀mú ìṣaajú nì kò ní àbùkù, ǹjẹ́ a kì bá ti wá àyè fún èkejì.

8. Nítorí tí o rí àbùkù lára wọn, ó wí pé,“Kíyèsí i ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí,ti èmi o bá ilé Ísírẹ́lìàti ilé Júdà dá májẹ̀mu títún.

9. Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mútí mo ti bá àwọn baba baba wọn dá,nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́ láti mú wọn jádekúrò ní Íjíbítì, nítorí wọn kò jẹ́ olótítọ́ sí májẹ̀mú mièmi kò sì ta wọ́n nu, ni Olúwa wíni Olúwa wí.

10. Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lìdá lẹ̀yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí.Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn,èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn,èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn,wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.

11. Olúkúlùkù kò ní tún máa kọ́ ara ìlú rẹ̀,tàbi olukulùkù arákùnrin rẹ̀, pé, ‘mọ Olúwa,’Nítorí pé gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí,láti kékere dé àgbà.

12. Nítorí pé èmi ó ṣáànu fún àìṣódodo wọn,àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àiṣedeede wọn lèmí ki yóò sì rántí mọ́.”

13. Ní èyí tí ó wí pé, Májẹ̀mu títún ó ti sọ ti ìṣáájú di ti láéláé. Ṣùgbọ́n èyí tí ó ń di i ti láéláé tí ó sì ń gbó, o múra àti di asán.