orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Ìrúbọ Kírísítì Lẹ́ẹ̀kan Ṣoṣo Fún Gbogbo Ènìyàn

1. Nítorí òfin, bí o ti ní òjìjì àwọn ohun rere ti ń bẹ̀ tí kì í ṣe àwòrán tóòtọ́ fún rere nǹkan náà, kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbàgbogbo lọdọ́ọ̀dún mu àwọn tí ń wá sibẹ̀ di pípé.

2. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a ba ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.

3. Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìranti ẹ̀ṣẹ̀ lọdọ́ọ̀dún.

4. Nítorí ko ṣeeṣe fún ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti ti ewúrẹ́ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò.

5. Nítorí náà nígbà tí Kísítì wá sí ayé, ó wí pé,“Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọrẹ,ṣùgbọ́n ara ni ìwọ ti pèsè fún mi;

6. Ẹbọ sísun àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ niìwọ kò ní inú dídùn sí.

7. Nígbà náà ni mo wí pé, ‘Kíyèsí i (nínú ìwé kíká ni a gbé kọọ́ nípa ti èmi)mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ ”

8. Nígbà tí o wí ni ìṣáajú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọ̀rẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).

9. Nígbà náà ni ó wí pé, “Kíyèsí i, mo de láti ṣe ìfẹ́ rẹ Ọlọ́run.” O mu ti ìṣáaju kúrò, kí a lè fi ìdí èkejì múlẹ̀.

10. Nípa ìfẹ́ náà ni a ti sọ wá di mímọ́ nípa ẹbọ ti Jésù Kírísítì fi ara rẹ̀ rú lẹ̀ẹ̀kanṣoṣo.

11. Àti olukulùkù àlùfáà sì ń dúró lójoojúmọ́ láti ṣiṣẹ́ ìsìn, ó sì ń ṣe ẹbọ kan náà nígbàkúgbà, tí kò lè mú ẹ̀ṣẹ̀ kúrò láé:

12. Ṣùgbọ́n òun, lẹ̀yìn ìgbà tí o ti rú ẹbọ kan fún ẹ̀ṣẹ̀ títí láé, o jòkòó lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run;

13. Láti ìgbà náà, ó rétí títí a o fi àwọn ọ̀ta rẹ̀ ṣe àpótí itísẹ̀ rẹ̀.

14. Nítorí nípa ẹbọ kan a ti mú àwọn tí a sọ di mímọ́ pé títí láé.

15. Ẹ̀mí mímọ́ sì ń jẹri fún wa pẹ̀lú: Nítorí lẹ̀yìn tí ó wí pé,

16. “Èyí ni májẹ̀mú ti èmi o ba wọn dálẹ́hìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí,èmi o fi òfin mi sí wọn ní ọkàn,inú wọn pẹ̀lú ni èmi o sì kọ wọn sí.”

17. “Ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àìṣedéédéwọn lèmi kì yóò sì rántí mọ́.”

18. Ṣùgbọ́n níbi tí ìmukúrò ìwọ̀nyí bá gbé wà, ìrubọ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò sí mọ́.

Ìpè Sí Ìforitì

19. Ará, ǹjẹ́ bí a ti ní ìgboyà láti wọ inú ibi mímọ́ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù,

20. Nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọja aṣọ ìkelé èyí yìí ní, ara rẹ̀;

21. Àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run;

22. Ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkan búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù.

23. Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìreti wa mu ṣinṣin ni àìsiyèméjì; (nítorí pé olóòtọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí).

24. Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere:

25. Kí a ma máa kọ ìpejọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni niyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ etílé.

26. Nítorí bí àwa ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́sẹ̀ lẹ̀yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

27. Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ní lẹ̀rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀ta run.

28. Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Móṣè, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta:

29. Mélòómélòó ni ẹ rò pé a o jẹ Olúwa rẹ̀ ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹgan ẹmi oore òfẹ́.

30. Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé: Ẹ̀san niti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi o gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.”

31. Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

32. Ṣùgbọ́n ẹ rántí ọjọ́ ìṣáájú nínú èyí tí, nígbà tí a ti ṣi yin lójú, ẹ fi ara da wàhálà ńlá ti ìjìyà;

33. Lápakan, nígbà tí a ṣọ yín di ìran wíwò nípa ẹ̀gàn àti ìpọ́njú; àti lápakan, nígbà tí ẹ̀yin di ẹ̀gbẹ àwọn tí a ṣe bẹ́ẹ si.

34. Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.

35. Nítorí náà ẹ má ṣe gbé ìgboyà yín sọnù, èyí ti o ni èrè ńlá.

36. Nítorí ẹ̀yin kò le ṣe aláìní suuru, nítorí ìgbà tí ẹ̀yin bá ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tan kí ẹ̀yin le gba ìlérí náà.

37. Nítorí ni ìwọ̀n ìgbà díẹ̀ sí i,“Ẹni náà ti ń bọ̀ yóò dé, kí yóò sì jáfara.

38. Ṣùgbọ́n olódodo ni yóò yè nípa ìgbàgbọ́:Ṣùgbọ́n bí o ba fà sẹ́yìn,ọkàn mi kò ní inú dídùn sí i.”

39. Ṣùgbọ́n àwa kò sí nínú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sínú ègbé; bí kò ṣe nínú àwọn tí o gbàgbọ́ sí ìgbàlà ọkàn.