orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Hébérù 7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Melikisédékì Jẹ́ Àlùfáà

1. Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹni tí ó pàdé Ábúráhámù bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un.

2. Ẹni tí Ábúráhámù sì pin ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún; lọ́nà èkíniní nínú ìtumọ̀ rẹ̀, “Ọba òdodo,” àti lẹ̀yìn náà pẹ̀lú, “ọba Sálẹ́mù,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.”

3. Láínì baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.

4. Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Ábúráhámù baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún.

5. Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Léfì, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Ábúráhámù jáde.

6. Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí,

7. láìsí ìjìyàn rárá ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè ni.

8. Àti níyin, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè nì.

9. Àti bí a ti lè wí, Léfì pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù.

10. Nítorí o sáa sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melikísédékì pàdé rẹ̀.

Jésù Fẹ́ràn Mélikisédékì

11. Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Léfì, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kínni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melikísédékì, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Árọ́nì?

12. Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin.

13. Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kòì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ.

14. Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Júdà ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mósè kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà.

15. Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà míràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melikísédékì.

16. Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin.

17. Nítorí a jẹri pé:“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipaṣẹ̀ ti Melikísédékì.”

18. Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìléera àti àìlérè rẹ̀.

19. (Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.

20. Níwọ̀n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni.

21. Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, ṣùgbọ́n ti òún jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nípa ẹni tí ó wí fún un pé,“Olúwa búra,kí yóò sì yí padà:‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”

22. Níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni Jésù ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.

23. Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú.

24. Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ nípò.

25. Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nipasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láàyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.

26. Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ;

27. Ẹni tí kò ní láti máa rúbọ lójojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ̀yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.

28. Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ̀yín òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.