Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1 Jòhánù 2:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jésù Kírísítì, olódodo nìkan.

2. Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.

3. Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́.

4. Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì sí nínú rẹ̀.

5. Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀.

6. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti rìn.

7. Ẹ̀yin olùfẹ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́.

8. Pẹ̀lúpẹ̀lú, òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín; èyí tí í ṣe òtítọ́ nínú rẹ̀ àti nínú yin, nítorí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ́ òtítọ́ sì tí ń tàn.

9. Ẹni tí o bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí o sì kóríra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn.

10. Ẹni tí o ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, o ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì sí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kóríra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkunkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.

12. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n,nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.

13. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe,Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n,nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba.

14. Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètékọṣe.Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,nítorí tí ẹ̀yin ni agbára,tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín,tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.

15. Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀.

16. Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kùfẹ́ ẹni ẹ̀sẹ̀, ìfẹ́kùfẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó se: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé.

17. Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kùfẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.

18. Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé Aṣòdìsí-Kírísítì ń bọ̀ wá, àní nísìnsin yìí, púpọ̀ Aṣòdì-sí-Kírísítì ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fí mọ́ pé ìgbà ìkẹ́yìn ni èyí.

Ka pipe ipin 1 Jòhánù 2