Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Rúùtù 2:13-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Rúùtù sì fèsì wí pé, “Kí èmi kí ó máa rí ojúrere láti ọ̀dọ̀ rẹ ṣíwájú sí i olúwa mi. Ìwọ ti tù mí nínú nípa sísọ ọ̀rọ̀ rere sí ìránṣẹ́-bìnrin rẹ, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé èmi kò tó ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ.”

14. Nígbà tí àkókò oúnjẹ sì tó, Bóásì sọ fún Rúùtù pé, “Wá gba ìwọ̀n àkàrà yí kí o sì fi run wáìnì kíkan.”Ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn olùkórè, Bóásì sì fún-un ní ọkà yíyan. Ó sì jẹ́, ó yó, ó sì tún ṣẹ́kù.

15. Nígbà tí ó sì dìde láti máa ṣa ọkà, Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ wí pé, “Bí ó tilẹ̀ ń ṣà láàárin oko ọkà pàápàá, ẹ má ṣe dí i lọ́wọ́.

16. Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣa, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.”

17. Rúùtù sì ń ṣa ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan (lítà méjìlélógún).

18. Ó sì gbé e lọ sí ìgboro, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí sà bi o tí pọ̀ tó, Rúùtù sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀.

19. Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣa ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.”Rúùtù sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bóásì ni òun ti ṣiṣẹ́ lónìí.”

20. Náómì sì wí fún-un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Náómì sì sọ ṣíwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tó láti ra ohun-ìní ìdílé padà.”

21. Rúùtù, ará Móábù sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣa ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ”

22. Náómì sì sọ fún Rúùtù, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”

23. Rúùtù sì bá àwọn ìránṣẹ́-bìnrin Bóásì ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà bálì àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.

Ka pipe ipin Rúùtù 2