orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àkókò Àti Ìgbà Wa Fún Ohun Gbogbo

1. Àsìkò wà fún ohun gbogboàti ìgbà fún gbogbo nǹkan ní abẹ́ ọ̀run.

2. Ìgbà láti bí àti ìgbà kíkú,ìgbà láti gbìn àti ìgbà láti fàtu.

3. Ìgbà láti pa àti ìgbà láti mú lára dáìgbà láti wó lulẹ̀ àti ìgbà láti kọ́.

4. Ìgbà láti ṣunkún àti ìgbà láti rín ẹ̀rínìgbà láti sọ̀fọ̀ àti ìgbà láti jó

5. Ìgbà láti tú òkúta ká àti ìgbà láti ṣà wọ́n jọìgbà láti ṣún mọ́ àti ìgbà láti fà ṣẹ́yìn

6. Ìgbà láti wá kiri àti ìgbà láti ṣàì wá kiriìgbà láti pamọ́ àti ìgbà láti jù nù,

7. Ìgbà láti ya àti ìgbà láti ránìgbà láti dákẹ́ àti ìgbà láti ṣọ̀rọ̀

8. Ìgbà láti níìfẹ́ àti ìgbà láti kóríraìgbà fún ogun àti ìgbà fún àlàáfíà.

9. Kí ni òṣìṣẹ́ jẹ ní èrè nínú wàhálà rẹ̀?

10. Mo ti rí àjàgà tí Ọlọ́run gbé lé ọmọ ènìyàn.

11. Ó ti ṣe ohun gbogbo dáradára ní àsìkò tirẹ̀, ó sì ti fi èrò nípa ayérayé sí ọkàn ọmọ ènìyàn, ṣíbẹ̀, wọn kò le ṣe àwárí ìdí ohun tí Ọlọ́run ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin.

12. Mo mọ̀ wí pé kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju pé kí inú wọn dùn kí wọn sì ṣe rere níwọ̀n ìgbà tí wọ́n sì wà láàyè.

13. Wí pé: kí olúkúlùkù le è jẹ, kí wọn sì mu, kí wọn sì rí ìtẹ́lọ́rùn nínú gbogbo iṣẹ́ wọn ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí jẹ́.

14. Mo mọ̀ wí pé ohun gbogbo tí Ọlọ́run ṣe ni yóò wà títí láé, kò sí ohun tí a lè fi kún un tàbí kí a yọ kúrò nínú rẹ̀. Ọlọ́run ṣe èyí kí ènìyàn le è ní ìbẹ̀rù rẹ̀ ni.

15. Ohun tí ó wà ti wà tẹ́lẹ̀,ohun tí ó ń bọ̀ wá ti wà tẹ́lẹ̀,Ọlọ́run yóò sì mú kí àwọn ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ṣẹ́yìn tún ṣẹlẹ̀

16. Mo sì tún rí ohun mìíràn níabẹ́ ọ̀run dípò ìdájọ́,òdodo ni ó wà ní bẹ̀ dípò ètò òtítọ́, ẹ̀ṣẹ̀ ní o wà ní bẹ̀.

17. Mo rò nínú ọkàn mi,“Ọlọ́run yóò mú ṣẹ sí ìdájọ́Olótìítọ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀,Nítorí pé àsìkò yóò wà fún gbogbo iṣẹ́,àti àsìkò fún gbogbo ìṣe.”

18. Mo tún ro pe “Ọlọ́run ń dán wa wò láti fi hàn wá wí pé bí ẹranko ni ènìyàn rí.

19. Ó ní láti jẹ́ ohun ìrántí pé ìpín ènìyàn rí bí i tẹranko ìpín ń dúró dè wọ́n. Bí ọ̀kan ti ń kú náà ni èkejì yóò kú. Àwọn méjèèjì ni irú èémí kan náà, ènìyàn kò ṣàn ju ẹranko lọ, nítorí pé aṣán ni yíyè jẹ́ fún wọn.

20. Ibì kan náà ni gbogbo wọn ń lọ, wọ́n wá láti inú erùpẹ̀, inú erùpẹ̀ náà ni wọn yóò tún padà sí.

21. Ta ni ó mọ̀ bóyá ẹ̀mí ènìyàn ń lọ sí òkè tí ẹ̀mí ẹranko sì ń lọ sí ìsàlẹ̀ nínú ilẹ̀ ní?”

22. Nígbà náà, ni mo wá ríi wí pé, kò sí ohun tí ó sàn fún ènìyàn ju kí ó gbádùn iṣẹ́rẹ̀, nítorí pé ìpín tirẹ̀ ni èyí. Tàbí ta ni ó le è mú kí ó rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn-in rẹ̀ kò sí!