orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Oníwàásù 11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

Àkàrà Lórí Omi:

1. Fún àkàrà rẹ ṣórí omi,nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò ríi padà

2. Fi ìpín fún méje, àní fún mẹ́jọ pẹ̀lú,nítorí ìwọ kò mọ ohun—ìparun tí ó le è wá ṣórí ilẹ̀

3. Bí àwọ̀ṣánmọ̀ bá kún fún omi,ayé ni wọ́n ń rọ òjò síBí igi wó sí ì hà Gúṣù tàbí sí ìhà àríwáníbi tí ó wó sí náà, ni yóò dùbúlẹ̀ sí.

4. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo afẹ́fẹ́ kò ní fúnrúgbìn;ẹnikẹ́ni tí ó bá ń wo àwọ̀ṣańmọ̀ kò ní kórè.

5. Gẹ́gẹ́ bí ìwọ kò ti ṣe mọ ojú ọ̀nà afẹ́fẹ́tàbí mọ bí ara tí ń dàgbà nínú ikùn ìyáarẹ̀,bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ kò le è ní òye iṣẹ́ Ọlọ́runẹlẹ́dàá ohun-gbogbo.

6. Fún irúgbìn rẹ ní òwúrọ̀ kùtùkùtù,má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ ṣọ̀lẹ ní àṣálẹ́,nítorí ìwọ kò mọ èyí tí yóò ṣe rerebóyá èyí tàbí ìyẹntàbí àwọn méjèèjì ni yóò ṣe dáradára bákàn náà.

Rántí Ẹlẹ́dàá Rẹ Ní Ìgbà Èwe Rẹ.

7. Ìmọ́lẹ̀ dùnÓ sì dára fún ojú láti rí oòrùn.

8. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn jẹ̀gbádùn gbogbo iye ọdúntí ó le è lò láyéṣùgbọ́n jẹ́ kí ó rántí ọjọ́ òkùnkùnnítorí wọn ó pọ̀Gbogbo ohun tí ó ń bọ̀ asán ni.

9. Jẹ́ kí inú rẹ dùn, ìwọ ọ̀dọ́mọdé ní ìgbà tí o wà ní èwekí o sì jẹ́ kí ọkàn rẹ fún ọ ní ayọ̀ ní ìgbà èwe rẹ.Tẹ̀lé ọ̀nà ọkàn rẹàti ohunkóhun tí ojú rẹ ríṣùgbọ́n mọ̀ dájú pé nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí niỌlọ́run yóò mú ọ wá sí ìdájọ́.

10. Nítorí náà, mú ìjayà kúrò ní ọkàn rẹkí o sì lé ìbànújẹ́ ara rẹ kúrònítorí èwe àti kékeré kò ní ìtumọ̀.