Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 9:44-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

44. Ábímélékì àti àwọn ọmọ ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sáré síwájú, wọ́n gba ẹnu ibodè ìlú náà, wọ́n sì dúró níbẹ̀. Àwọn ẹgbẹ́ méjì tókù sì sáré sí àwọn tó wà ní oko wọ́n sì gbógun tì wọ́n.

45. Ní gbogbo ọjọ́ náà ni Ábímélékì fi bá àwọn ará ìlú náà jà, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì pa àwọn ènìyàn ìlú náà ó wó ìlú náà palẹ̀ pátapáta ó sì fọ́n iyọ̀ sí i.

46. Àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, wọ́n sá lọ fún ààbò sí inú ilé ìsọ́ agbára Ọlọ́run Bérítì (El-Bérítì).

47. Nígbà tí wọ́n sọ fún Ábímélékì pé àwọn ènìyàn ilé ìṣọ́ Ṣékémù kó ara wọn jọ pọ̀.

48. Òun àti gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gun òkè Sálímónì lọ. Ó gé àwọn ẹ̀ka díẹ̀ pẹ̀lú àáké, ó gbé àwọn ẹ̀ka wọ̀nyí sí èjìká rẹ̀. Ó sọ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe ohun tí ẹ rí tí mo ń ṣe yìí ní kíákíá.”

49. Báyìí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gé àwọn ẹ̀ka igi wọn tẹ̀lé Ábímélékì. Wọ́n kó wọn ti ilé ìṣọ́ agbára níbi tí àwọn ènìyàn sá pamọ́ sí wọ́n sì fi iná síi pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà níbẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ó tó ẹgbẹ̀rún ènìyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin sì kú.

50. Ábímélékì tún lọ sí Tébésì, ó yí ìlú náà ká pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.

51. Ilé ìṣọ́ kan tí ó ní agbára sì wà nínú ìlú náà. Gbogbo àwọn ènìyàn ìlú náà ọkùnrin àti obìnrin sá sínú ilé ìṣọ́ náà. Wọ́n ti ara wọn mọ́ ibẹ̀ wọ́n sì sá lọ sí inú àjà ilé ìṣọ́ náà.

52. Ábímélékì lọ sí ìṣàlẹ̀ ilé ìṣọ́ náà, ó sì ń bá a jà. Ṣùgbọ́n bí ó ti súnmọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ìṣọ́ náà láti dáná sun ún,

53. obìnrin kan sọ ọmọ ọlọ lé e lórí, ó sì fọ́ ọ ní agbárí.

54. Ní ojú kan náà ni ó pe ẹni tí ó ru àpáta rẹ̀ pé, “Yára yọ idà rẹ kí o sì pa mí, kí wọn má ba à sọ pé, ‘Obìnrin ni ó pa á.’ ” Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sì fi ọ̀kọ̀ gún-un ó sì kú.

55. Nígbà tí àwọn ará Ísírẹ́lì rí i pé Ábímélékì kú, olúkúlùkù wọn padà sí ilé rẹ̀.

56. Báyìí ni Ọlọ́run san ẹ̀san ìwà búburú ti Ábímélékì hù sí baba rẹ̀ ní ti pípa tí ó pa, àwọn àádọ́rin (70) arákùnrin rẹ̀.

57. Ọlọ́run jẹ́ kí ìwà búburú àwọn ará Ṣékémù pẹ̀lú padà sí orí wọn. Ègún Jótamù ọmọ Jérú-Báálì pàápàá wá sí orí wọn.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 9