Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 4:2-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Nítorí náà Olúwa jẹ́kí Jábínì, ọba àwọn Kénánì, ẹni tí ó jọba ní Haṣórì, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ṣísérà ẹni tí ń gbé Hároṣeti-Hágóyímù.

3. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Ísírẹ́lì lójú gidigidi fún ogún ọdún. Ísírẹ́lì ké pe Olúwa fún ìrànlọ́wọ́.

4. Dèbórà, wòlíì-obìnrin, aya Lápídótì ni olórí àti asíwájú àwọn ará Ísírẹ́lì ní àsìkò náà.

5. Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a ṣọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Dèbórà láàárin Rámà àti Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù, àwọn ará Ísírẹ́lì a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn Olúwa láti ẹnu rẹ̀.

6. Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Bárákì ọmọ Ábínóámù ẹni tí ń gbé ní Kádésì ní ilẹ̀ Náfítalì, ó sì wí fún-un pé Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa á ní àṣẹ fún-un pé kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Náfítalì àti ẹ̀yà Ṣébúlúnì bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì ṣíwájú wọn lọ sí òkè Tábórì.

7. Èmi yóò sì fa Sísérà olórí ogun Jábínì, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kíṣónì èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.

8. Bárákì sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”

9. Dèbórà dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí Olúwa yóò fi Sísérà lé obìnrin lọ́wọ́” Báyìí Dèbórà bá Bárákì lọ sí Kédésì.

10. Nígbà tí Bárákì pe ẹ̀yà ṣébúlúnì àti ẹ̀yà Náfítalì sí Kédésì ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Dèbórà pẹ̀lú bá wọn lọ.

11. Ní àsìkò yìí Hébérì, ọ̀kan nínú ẹ̀yà Kẹ́nì, ti ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Kénì, òun sì ń gbé ibòmíràn títí dé ibi igi óákù Ṣánanímù, tí ó wà ni agbégbé Kédésì (àwọn ẹ̀yà Kénì jẹ́ ìran Hóbábù ẹni tí i ṣe àna Móṣè).

12. Nígbà tí a sọ fún Ṣísérà pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti kó ogun jọ sí òkè Tábósì,

13. Ṣísérà kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run (900) àti gbogbo àwọn ènìyàn (ọmọ ogun) tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì tí àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ̀dọ̀ Kíṣónì.

14. Dèbórà sì wí fún Bárákì pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Ṣísérà lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ ṣíwájú rẹ.” Bárákì sì ṣíwájú, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀le e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tábórì.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 4