Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 4:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Dèbórà sì wí fún Bárákì pé, “Lọ! Lónìí ni Olúwa fi Ṣísérà lé ọ lọ́wọ́, Olúwa ti lọ ṣíwájú rẹ.” Bárákì sì ṣíwájú, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀le e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tábórì.

15. Olúwa sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárin ogun Sísérà, Olúwa sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sísérà àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Bárákì. Sísérà sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ó sì fi ẹṣẹ̀ sálọ.

16. Bárákì àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀ èdè, títí ó fi pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Ṣísérà kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láàyè.

17. Ṣùgbọ́n Ṣísérà ti fi ẹṣẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáélìa aya Hébérì ẹ̀yà Kénì: nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àlàáfíà wà láàárin Jábínì ọba Háṣórì àti ìdílé Hébérì ti ẹ̀yà Kénì.

18. Jáélì sì jáde síta láti pàdé Sísérà, ó sì wí fún-un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, Olúwa mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.

19. Sísérà wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì sí awọ wàrà kan, ó sì fún-un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.

20. Sísérà sọ fún Jáélì pé, “Kí ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”

21. Ṣùgbọ́n Jáélì ìyàwó Hébérì mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó ṣùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin ó sì kú.

Ka pipe ipin Onídájọ́ 4