Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Onídájọ́ 20:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Àwọn ọmo Bẹ́ńjámínì sì jáde láti Gíbíà wá wọ́n sì pa àwọn ọmọ ẹgbàá mọ́kànlá ọkùnrin nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ojú ogun ní ọjọ́ náà.

22. Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì mú ara wọn lọ́kàn le, wọ́n sì tún dúró sí ipò wọn ní ibi tí wọ́n dúró sí ní ọjọ́ àkọ́kọ́.

23. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì lọ wọ́n sunkún ní iwájú Olúwa títí oòrùn fi wọ̀, wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. Wọ́n ni, “Ṣé kí àwa tún gòkè lọ kí a sì bá àwọn ará Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa jà?” Olúwa dáhùn pé, “Lọ bá wọn jà.”

24. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún súnmọ́ tòsí àwọn ará Bẹ́ńjámínì ní ọjọ́ kejì.

25. Ní ọjọ́ yìí nígbà tí ará Bẹ́ńjámínì jáde sí wọn láti Gíbíà, láti dojú kọ wọn, wọ́n pa ẹgbẹ̀sán (18,000) ọkùnrin Ísírẹ́lì, gbogbo wọn jẹ́ jagunjagun tí ń lo idà.

26. Nígbà náà ni gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àní gbogbo àwọn ènìyàn, gòkè lọ sí Bẹ́tẹ́lì, níbẹ̀ ni wọ́n jókòó tí wọ́n sì ń sunkún níwájú Olúwa. Wọ́n gbààwẹ̀ ní ọjọ́ náà títí di àṣálẹ́, wọ́n sì rú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà (ọrẹ ìrẹ́pọ̀) sí Olúwa.

27. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa. (Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run wà níbẹ̀,

28. Fínéhásì ọmọ Élíásárì ọmọ Árónì, ní ń ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní iwájú rẹ̀.) Wọ́n béèrè pé, “Ṣe àwa tún le lọ sí ogun pẹ̀lú Bẹ́ńjámínì arákùnrin wa tàbí kí a má lọ?” Olúwa dáhùn pé, “Ẹ lọ nítorí ní ọ̀la ni èmi yóò fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́.”

Ka pipe ipin Onídájọ́ 20