Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ọbadáyà 1:3-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’

4. Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,Bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárin àwọn ìràwọ̀,Láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”ni Olúwa wí.

5. “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,Bí àwọn ọlọ́sà ní òru,Áà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:ṣé wọn kò jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,ṣé wọn kò ni fi èésẹ́ èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?

6. Báwo ni a ṣe se àwárí nǹkan Ísọ̀tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde

7. Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

8. Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n Édómù run,àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Ísọ̀?

9. A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Témánì,gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Ísọ̀ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.

10. Nítorí ìwà ipá sí Jákọ́bù arákùnrin rẹ,ìtìjú yóò bò ọ,a ó sì pa ọ run títí láé.

11. Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apákan,ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹtí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jérúsálẹ́mù,ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.

12. Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà,ní ọjọ́ ìparun wọnìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ní ọjọ́ wàhálà wọn.

Ka pipe ipin Ọbadáyà 1