Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 8:17-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi.

18. Mo sì ti gba àwọn ọmọ Léfì dípò gbogbo àkọ́bí ọmọ ọkùnrin nínú Isireli

19. Nínú Ísírẹ́lì, mo fi àwọn ọmọ Léfì fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn láti máa ṣiṣẹ́ nínú àgọ́ ìpàdé fun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti láti máa ṣe ètùtù fún wọn kí àjàkálẹ̀-àrùn má ba à kọlu àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n bá súnmọ́ ibi mímọ́.”

20. Mósè, Árónì àti gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì sì ṣe fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

21. Àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn. Árónì sì mú wọn wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ fífì níwájú Olúwa, Árónì sì ṣe ètùtù fún wọn láti wẹ̀ wọ́n mọ́.

22. Lẹ́yìn èyí àwọn ọmọ Léfì lọ sínú àgọ́ ìpàdé láti lọ máa ṣiṣẹ́ wọn lábẹ́ àbojútó Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n ṣe fún àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

23. Olúwa sọ fún Mósè pé,

24. “Èyí ni ohun tó jẹ mọ́ àwọn ọmọ Léfì: Láti ọmọ ọdún kẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni kí ó máa kópa nínú iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé.

25. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá ti pé ọmọ àádọ́ta ọdún gbọdọ̀ síwọ́ nínú iṣẹ́ ojoojúmọ́ wọn nínú àgọ́, kí wọ́n sì má ṣiṣẹ́ mọ́

26. Wọ́n le máa ran àwọn arákùnrin wọn lọ́wọ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé ṣùgbọ́n àwọn fúnra wọn kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Báyìí ni kí o ṣe pín iṣẹ́ fún àwọn ọmọ Léfì.”

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 8