Nítorí pé gbogbo àkọ́bí ọmọ lọ́kùnrin ní Ísírẹ́lì jẹ́ tèmi, ti ènìyàn àti ti ẹranko, láti ọjọ́ tí mo ti pa gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Éjíbítì ni mo ti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ara mi.