Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Nọ́ḿbà 4:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé:

2. “Ka iye àwọn ọmọ Kóhátì láàrin àwọn ọmọ Léfì nípa ilé baba wọn àti ìdílé wọn.

3. Ka gbogbo ọkùnrin láti ọmọ ọgbọ̀n ọdún títí dé àádọ́ta ọdún gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú Àgọ́ Ìpàdé.

4. “Wọ̀nyí ni iṣẹ́ àwọn ọmọ Kóhátì, láti tọ́jú àwọn ohun èlò mímọ́ jùlọ.

5. Nígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò wọ inú rẹ̀, wọn yóò sí aṣọ ìbòrí rẹ̀, wọn yóò sì fi bo àpótí ẹ̀rí.

6. Wọn yóò sì fi awọ ewúrẹ́ bò ó, lórí awọ ewúrẹ́ yìí ni wọn ó tẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

7. Lórí tabilì ìfihàn ni kí wọn ó na aṣọ aláró kan sí, wọn ó sì kó àwọn àwo, páànù, àwokòtò àti ìgò fún ọrẹ ohun mímu; àkàrà tó sì máa ń wà níbẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà gbọ́dọ̀ wà níbẹ̀.

8. Lórí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọn yóò da, wọn ó tún fi awọ ewúrẹ́ bò ó, wọn ó sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

9. “Kí wọn kí ó fi aṣọ aláwọ̀ búlù bọ ọ̀pá fìtílà àti fìtílà rẹ̀, àti àwo ìkó ẹ̀mu sí, àti gbogbo ohun èlò òróró rẹ̀, èyí tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

10. Kí wọn ó fi awọ ẹran yí fìtílà àti gbogbo ohun èlò rẹ, kí wọn kí ó sì gbé e lé orí férémù tí wọn yóò fi gbé e.

11. “Ní orí pẹpẹ wúrà ni kí wọn ó tẹ́ aṣọ aláró kan sí, wọn yóò sì fi bò ó, kí wọ́n sì fi òpó rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

12. “Kí wọn kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn ní ibi mímọ́, kí wọn ó fi aṣọ aláwọ̀ búlúù yìí, kí wọn ó sì fi bò ó, kí wọn ó sì fi gbé wọn ka orí férémù.

13. “Kí wọn ó kó eérú kúrò lórí pẹpẹ idẹ, kí wọn ó sì tẹ́ aṣọ aláwọ̀ àlùkò lé e lórí.

14. Nígbà náà ni kí wọn ó kó gbogbo ohun èèlò fún iṣẹ́ ìsìn níbi pẹpẹ, títí dórí àwo iná, fọ́ọ̀kì ẹran, ọkọ́ eérú àti àwo kòtò. Kí wọn ó fi àwọ ewúrẹ́ bo gbogbo rẹ̀, kí wọn ó sì fi òpo rẹ̀ bọ ààyè rẹ̀.

15. “Lẹ́yìn tí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti parí bíbo ibi mímọ́ àti gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́, nígbà tí àgọ́ bá sì ṣetán láti tẹ̀ṣíwájú, kí àwọn ọmọ Kóhátì bọ́ ṣíwájú láti gbé e, ṣùgbọ́n wọn kò gbọdọ̀ fọwọ́ kan ohun mímọ́ kankan, bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn ó kú. Àwọn ọmọ Kóhátì ni yóò gbé gbogbo ohun tó wà nínú Àgọ́ Ìpàdé.

16. “Iṣẹ́ Élíásárì ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà ni ṣíṣe àmójútó òróró fìtílà, tùràrí dídùn, ẹbọ ohun jíjẹ ìgbà gbogbo àti òróró ìtasórí: Kí ó jẹ́ alábojútó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ àgọ́ àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun èèlò ibi mímọ́.”

17. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì pé,

Ka pipe ipin Nọ́ḿbà 4